You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yomi Fabiyi: Èmi ti dáríjì ẹ́, kí ìwọ náà jọ̀wọ́ dáríjì mí
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Gbajugbaja osere, Yomi Fabiyi ti kesi akẹgbẹ rẹ, Toyin Abraham wi pe ki wọn pari ija to wa laarin awọn mejeeji.
Yomi Fabiyi tọrọ idariji lọwọ Toyin Abraham lori ẹrọ ikansiraẹni Instagram rẹ, ki Toyin si fọwọ wọnu ninu ọdun tuntun.
Fabiyi fi kun un wi pe gbogbo ẹṣẹ ti Toyin ṣẹ oun ni oun ti dariji, ki Toyin naa ṣe bakan naa, ki ohun gbogbo si pada si ipo laarin wọn.
Ti a ko ba gbagbe, ija laarin Toyin Abraham ati Yomi Fabiyi bẹrẹ ni nkan bii ọdun diẹ sẹyin, lẹyin ti Yomi Fabiyi pe Toyin Abraham ni alagabagebe nitori ija to wa laaarin Toyin Abraham ati oṣerebinrin miiran, Mercy Aigbe.