Iyabo Ojo: Èéti jẹ́ tí Iyabọ Ojo fẹ́ kí ọmọ rẹ̀, Priscilla lọ sílé ọkọ ní ẹni ọdún 24?

Ṣebi idunnu gbogbo abiyamọ ni pe ki ọmọ wọn o dagba, ki iṣe rẹ si ṣoju wọn.

Lara iṣerere ọmọ ti obi ma n gba ni adura ni ọjọ igbeyawo.

Eyi gan-an lo difa fun gbajugbaja oṣerebinrin, Iyabo Ojo to gba ọmọ rẹ obinrin, Priscila ni imọran pe ko tete wọ ile ọkọ lo dara.

Ninu fidio naa ni Iyabo ti n ba ọmọ rẹ sọrọ, ati awọn ọmọbinrin mii to n gbe pẹlu rẹ pe ki obinrin tete wọ ile ọkọ lo dara.

Ninu ijiroro ti wọn ṣe tẹrin-tẹrin ni Iyabo ti beere lọwọ Priscila pe ọmọ ọdun melo ni oun sọ fun pe ko lọ sile ọkọ.

Ọmọ naa dahun pe ọdun mẹrindinlogoji, amọ kia ni Iyabọ taka rẹ danu pe oun kọ ọ.

Iyabọ Ojo dahun pe ti ọmọ naa ba ti pe ọdun mẹtalelogun ni ko ti ni afẹsọna; ko ṣe igbeyawo ni ẹni ọdun mẹrindinlogun, ko si bimọ ni ẹni ọdun marundinlọgbọn.

O fikun ọrọ rẹ pe o le gbe ọmọ wa fun oun lati ma a tọju, ki oun ati ọkọ rẹ le gbadun ara wọn.

Priscilla Ojo jẹ ẹni ogun ọdun lọwọlọwọ.

Botilẹ jẹ pe Iyabọ sọ pe oun ko fi dandan mu wọn, o ni ara oun ti wa lọna lati mu aṣọ ẹbi fun ayẹyẹ igbeyawo.

"Ọdun mẹtalelogun ni mo wa nigba ti mo bi ọ."

Bẹẹ lo fun ẹnikọọkan awọn ọmọbinrin to wa ninu yaara naa ni gbedeke ọdun to ku fun ẹnikọọkan wọn lati lọ sile ọkọ.

Abiyamọ naa ni oun ko fẹ ki wọn o darugbo ki wọn o to ṣe igbeyawo.

Ko tan sibẹ o, o tun gba wọn ni imọran pe wọn ko gbọdọ rinrinajo ifẹ pẹlu ọkunrin kankan ti ko ba ni i fẹ wọn ni iyawo.

Yatọ si pe ọmọ n rele ọkọ tabi fẹ iyawo, ọjọ iwuri gba a lo ma n jẹ fun awọn obi. Ti wọn si ma n nawo, nara lasiko igbeaywo ọmọ wọn.