Nollywood, Yollywood: Tayo Sobola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ṣótáyọ̀ Gaga ní wọ́n ti fi Òun jẹ ìyá Ọba ní Nasarawa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọpọ awọn ololufẹ gbajugbaja oṣere tiata Yoruba ni, Tayọ Sobọla ti ọpọ mọ si Ṣotayọ Gaga ni ko lee pa idunnu wọn mọra bayii.

Eyi ko ṣeyin igba ti eekan oṣere sinima naa kede loju opo Instagram rẹ ni ọjọ diẹ sẹyin pe wọn ti fi oun jẹ Iya oba ni ilu Uke ni ipinlẹ Nasarawa.

Sotayo Gaga ni Emir ti ilu Uke, Abdullah Hassan lo fi oun jẹ oye tuntun naa ni aafin rẹ.

Sotayo ni lede Hausa, orukọ oye naa ni Sarauniya to tumọ si iya ọba.

Igbesẹ nla lọpọ awọn ololufẹ rẹ ri eyi si nitori pe gẹgẹ bi awọn kan ninu wọn ṣe sọ ninu idahun wọn si atẹjade rẹ naa, o fihan pe awọn ara oke ọya pẹlu n gbadun iṣẹ ọwọ rẹ, wọn si mọ riri rẹ pẹlu.

Lara awọn to wa nibi ayẹyẹ naa ni Ambasadọ Sadiq Ibrahim atawọn eekan ọmọ ilu naa.