European Super League: Arsenal, Man United, Man City, Real Madrid, Barcelona fẹ́ dá ìdíje líìgì tuntun sílẹ̀ ní Yúróòpù

Ni ọjọ Aiku ni iroyin kan gbode lagbe ere bọọlu lagbaye, papaa julọ nilẹ Yuropu pe awọn eekan ẹgbẹ agbabọọlu kan ti fẹ yapa.

Wọn ni wọn fẹ lọ da liigi agba tuntun silẹ nilẹ Yuroopu eyi ti wọn pe ni European Super league.

Iroyin naa burẹkẹ sii pẹlu bi awọn agba ọjẹ ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa lati liigi Premiership ni ilẹ Gẹẹsi ṣe kede ati darapọ mọ liigi tuntun naa.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa naa ni Arsenal, Chelsea, Manchester city, Manchester United, Liverpool ati Tottenham.

Bawo lọrọ naa ṣe bẹrẹ?

Ni oṣu kẹwaa, ọdun to kọja ni igbesẹ kọkọ bẹrẹ pẹlu ijiroro to lọwọ ileeṣẹ iṣuna kan ti orukọ rẹ n jẹ JP Morgan ninu.

Koko apero naa ni lati gbe idije kan kalẹ lati rọpo idije Champions League ni ilẹ Yuroopu ti owo ori rẹ yoo si to biliọnu mẹfa o le ẹgbẹta miliọnu pọun.

Ajọ UEFA gbe igbesẹ lati gbe idije Champions League tuntun pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrindinlogoji.

Eyi n waye pẹlu awọn atunṣe tuntun ti wọn gbero lati kede lọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹrin.

Kini erongba wọn fun liigi tuntun yii?

Ero wọn ni pe eyi yoo wawọ erongba idije Super league tuntun naa bọlẹ ṣugbọn ko dabi ẹni pe awọn atunto naa de agbeji ara agba ọjẹ ẹgbẹ agbabọọlu mejila to wa nidi idasilẹ liigi agba tuntun naa.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu wo lo wa nidi idasilẹ liigi European Super League?

Arsenal, Chelsea, Liverpool, Manchester United, Manchester City ati Tottenham wa lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejila to ti buwọlu idasilẹ liigi tuntun naa.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu liigi Premiership ti ilẹ Gẹẹsi naa yoo dara pọ mọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii AC Milan, Athletico Madrid, Barcelona, Inter Milan, Juventus ati Real Madrid fun idasilẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ajọ idasilẹ liigi tuntun ọhun ti wọn pe ni European Super league, ESL ni awọn ẹgbẹ agbabọọlu naa ti gba lati da liigi naa silẹ ti ifẹsẹwọnsẹ wọn yoo si maa waye ni aarin ọsẹ.

Kini yoo ṣẹlẹ lẹyin idasilẹ naa?

Amọṣa wọn yoo ṣi maa tẹsiwaju lati kopa ninu idije liigi orilẹede ọkọọkan wọn.

O ni liigi tuntun naa yoo bẹrẹ ni kanmọkia ti aaye rẹ ba ti yọ ati pe wọn n reti awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹta miran lati darapọ laipẹ.

Bakan naa ni wọn tun n gbero ati da idije tawọn ẹgbẹ agbabọọlu obinrin silẹ pẹlu.

Bawo ni ilana ati agbekalẹ rẹ yoo ṣe ri?

Liigi agba ọjẹ ilẹ Yuroopu naa, European Super league, ESL yoo fi aaye silẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu ogun lati kopa.

Egbẹ agbabọọlu mejila ti wa nikalẹ, pẹlu mẹta miran ti wọn n reti ṣugbọn ti wọn ko tii darukọ wọn, atawọn marun miran ti yoo maa kopa pẹlu bi wọn ba ṣe kogoja si lọdọọdun.

Isọri meji ni wọn yoo pin wọn si pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu mẹwaa-mẹwaa ni isọri kọọkan lati maa figagbaga bẹrẹ lati oṣu kẹjọ ọdọọdun.

Awọn mẹta to ba moke ni ọkọọkan isọri naa yoo wọle fun ipele kọta faina.

Ipele yii ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ba wa ni ipo kẹrin ati ikarun lawọn isọri mejeeji yoo tun forikori lati mu meji ti yoo daraps mọ awọn mẹfa akọkọ ni ipele kọta faina.

Lati ibẹ lọ ifẹsẹwọnsẹ rẹ yoo farajọ ti idije Champions League to wa nilẹ bayii.

Ajọ iṣakoso ESL ni owo ti yoo maa wọle yoo gbe pẹẹli ju ti Champions league lọ, eyi to tumọ si owo pupọ si fawọn ẹgbẹ agbabọọlu to nkopa.

Ariwisi wo lo ti n jẹyọ?

Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Yuroopu, ajọ to n ṣamojuto bọọlu liigi premiership nilẹ Gẹẹsi pẹlu olotu ijsba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson wa lara awọn to ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.

Ajọ UEFA ni oun yoo lo "gbogbo ọna to ba yẹ" lati fi dawọ igbesẹ naa duro.

Bẹẹni iroyin n jẹ ko di mimọ pe inu awọn eekan lagbo iṣakoso ere bọọlu ni UEFA ko dun si igbesẹ naa.

Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ni igbesẹ naa yoo "ṣe akoba fun ere bọọlu" ati pe ijọba ilẹ Gẹẹsi yoo ṣe atilẹyin fun awọn alaṣẹ ere bọọlu "ninu igbesẹ gbogbo ti wọn ba fẹ gbe"

O fi kun un pe "Gbogbo awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti ọrọ kan gbọdọ jẹjọ niwaju awọn ololufẹ wọn ati gbogbo ololufẹ ere bọọlu lagbaye ki wọn to tun gbe igbesẹ yoowu lori rẹ."

Ki lawọn alaṣẹ Super league n sọ bayii?

Aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid, Florentino Perez, to jẹ alaga akọkọ fun ajọ liigi bọọlu ni Yuroopu, ESL ṣalaye pe idije tuntun naa "yoo ṣe iranwọ fun ere bọọlu lẹka gbogbo."

Alaga ẹgbẹ agbabọọlu Juventus Andrea Agnelli ṣalaye pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejila naa" parapọ lasiko to ṣe pataki yii lati mu ayipada ba ere bọọlu ni ilẹ Yuroopu, lati gbe ẹsẹ ere idaraya ti a fẹran le pepele to dara fun ọjọ iwaju."

Alaga ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Joel Glazer ni yoo jẹ igbakeji liigi tuntun naa.

O ni: "Liigi Super League yoo ṣina tuntun fun ere bọọlu nilẹ Yuroopu, nipa ṣiṣeto idije ti ko lẹlẹgbẹ lagbaye, pẹlu afikun owo fun idagbasoke ere bọọlu."