Yoruba Nation: Ẹni tó máa kú ko kú, ẹni tó máa kù ko kù, ẹ jẹ́ ká jà fún ominira - Ọba Adetokunbo Tejuosoho

Ori ade kan ti sọ pe awọn eeyan bi oun ko nibi kankan lati salọ, ṣugbọn awọn ti ṣetan lati fi ẹmi wọn lelẹ ki ilẹ Yoruba le gba ominira lọwọ awọn to n ni aye wọn lara.

Ọba Adetokunbo Tejuosoho, Olu Orile Kemta lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba ni idahun si ọrọ minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed.

Ṣaaju ni Lai Mohammed ti kọkọ sọ pe ti gbogbo awọn to n lọgun Yoruba Nation ni yoo salọ ti ọrọ naa ba bẹyin yọ.

Ṣugbọn Ọba Orile kemta ti fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ, koda o ni awọn eeyan kan tilẹ ti n salọ kuro ni Naijiria tẹlẹ nitori bi gbogbo nnkan ṣe ri, paapaa nipa ti eto abo to mẹhẹ.

O ni "Ẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn kan ji odidi Ọba kan gbe nipinlẹ Ekiti, iyẹn nigba ti wọn ti kọkọ gbiyanju lati ji Ọba mii gbe ṣaaju."

"Bo tilẹ jẹ pe baba ni Lai Mohammed jẹ, igbagbọ temi ni pe o yẹ ko gbiyanju lati pẹtu si awọn eeyan ninu ni, kii ṣe ko maa sọ pe awọn kan yoo salọ."

Tejusosho tẹsiwaju pe "Awọn ajinigbe n wọ inu aafin lati ji ori odidi ade gbe, ẹ wa sọ pe ki awọn ajijagbara ma sọrọ... Nibo la n salọ gan, ẹni to maa kú ko kú, ẹni to maa kù ko kù, ẹ jẹ ka ja fun ominira!"

Tejuosho ni bi ọrọ ọhun ṣe n lọ yii, awọn ara ilu ti n ni igbagbọ ninu awọn eeyan bi Sunday Igboho ju igbagbọ ti wọn ni ninu ijọba lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni lootọ ni pe ijọba to wa lode jogun ba awọn iṣoro to wa ni Naijiria, ṣugbọn nigba ti wọn n ṣe ipolongo ibo, ileri ayipada 'change' ni wọn ṣe fun awọn eeyan ilu.

Idi si ree ti awọn araalu ṣe ni igbagbọ ninu wọn ṣaaju.

Oba yii fi kun un pe o yẹ ki ijọba pe ipade apero, ki gbogbo ẹya to wa ni Naijiria sọ ohun ti wọn n fẹ ki wọn si ṣe atunto, bi bẹẹ kọ, ki onikaluku maa lọ ni ilọ tirẹ.

Ni ti pe maa jo lọ mo n wo ẹyin rẹ ni ọrọ awọn to n pe fun ominira ilẹ Yoruba, Ọba Tejuosho ni ko ri bẹẹ nitori awọn to ni ifẹ awọn aaralu lọkan lo n pe fun ominira.

O ṣalaye pe "Ko si ẹni to n gbadura fun ogun, ṣugbọn ti a ko ba fẹ ogun, o yẹ ki a yanju ogun abẹle to n ja wa, ki a si ṣẹ atunto."

"Kii ṣe ẹbi awọn to n pe fun ipinya, ṣugbọn wọn gbe igbesẹ naa nitori wọn ti sun kan ogiri."

Ọba Tejuosho paro ọrọ rẹ pe oun ko gbadura fun wahala, ṣugbọn ti ọrọ naa ba gbọna mii yọ, oun ko ni ibi kankan ti oun yoo salọ lodi si ọrọ ti Lai Mohammed sọ nipa awọn to n pe fun iyapa.