You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde and BCOS staff quaters: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde ní fẹ́ wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati olu ilu ipinlẹ Oyo sọ pe Gomina Seyi Makinde ti paṣẹ pe ki wọn wo ileegbe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ iroyin BCOS to wa ni agbegbe Basorun niluu Ibadan.
Ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin ni a gbọ pe ijọba Makinde fẹ da ile naa wo.
Ko si ẹni to le sọ pato ohun ti ijọba fẹ fi ilẹ naa ṣe ti wọn ba wo ile to wa lori rẹ tan.
- "Seyi Makinde ló ṣàtìlẹyìn ètò ààbò fún ìwọ́de Oduduwa Nation"
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta
- Sunday Igboho kò ṣẹ̀ s‘òfin, àwọn ìbátán rẹ̀ ló ń dààbò bò l‘Oke Ogun - Yemi Farounbi
- Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ gbọ́dọ̀ fí ipò sílẹ̀ nítórí ó kùnà láti dẹ́kun ìpàníyàn ní Ibarapa - Gani Adams
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Èèmọ̀ wọ̀lú, Ajínigbé fo ògiri wọnú ààfin, wọ́n jí oríadé gbé l'Ekiti
Amọ, awọn kan sọ pe ijọba fẹ fi ilẹ to wa layinka ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS ati ilẹ ti ileegbe wọn lori rẹ kọ ile gbigbe nla ni.
Iroyin kan tiẹ sọ pe agbaṣeṣe ti ijọba gbe iṣẹ ile wiwo ọhun le lọwọ ti ko katakata lọ sibẹ, ki wọn bẹrẹ iṣẹ loku.
Oṣiṣẹ BCOS kan to ba awọn akọroyin sọrọ ṣugbọn ti ko darukọ ara rẹ ni ijọba ko fawọn olugbe ile naa ni iwe lati kuro nile ọhun.
O ni iṣoro airilegbe ni yoo lawọn oṣiṣẹ naa yoo doju kọ ti ijọba ba wo ileegbe wọn nitori wọn ko lowo lati gba ile to dara lagbegbe Basorun ti BCOS wa.
Ẹwẹ, igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ igbohun safẹfẹ BCOS ti sọ pe iru funfun balau ni iroyin to lu ori ayelujara pe ijọba ipinlẹ Oyo wo ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS.
Ninu atẹjade ọhun ti ọga agba BCOS buwọlu, alaga ileeṣẹ igbohun safẹfẹ. Ọmọba Dotun Oyelade, sọ pe loorekoore ni igbimọ alaṣẹ BCOS maa n sọ erongba ijọba lori ile ti wọn n gbe fun wọn.
- Wo àwọn àmì mẹ́jọ ti o lè fi mọ̀ pé ọkọ tàbí aya rẹ ti ń ṣe ìta
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
Ọmọba Oyelade ni igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ iroyin naa ko ni jẹ ki igbesẹ kankan ti ijọba ba fẹ gbe pa awọn oṣiṣẹ BCOS lara.
Ọga agba naa rọ awọn oṣiṣẹ BCOS atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹka-jẹka lati maa ka iroyin naa kun.
Amọ, o ṣalaye pe asọyepọ yoo waye pẹlu awọn oṣiṣẹ lori ileegbe nla ti ijọba n gbero lati kọ sori ilẹ to wa lẹgbẹ ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS ti ijọba ti gba tipẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Oyo, Taiwo Adisa sọ fun BBC Yoruba pe ko si otitọ kankan ninu iroyin naa.
''Ijọba ko fẹ wo ileegbe BCOS ni Ibadan, ilẹ ti ijọba ti gba tipẹ lẹgbẹ ileegbe BCOS ni ijọba fẹ kọ ileegbe nla le lori.
Taiwo Adisa tun ni: Ohun ti ijọba tun fẹ ṣe ni pe ki wọn tun awọn ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS ti ko dara loju to ṣe ki ibẹ le ba maa wu awọn ti ijọba ba fẹ ta ilẹ tabi ile tuntun fun.
Ijọba fẹ ṣe eyi nitori nibẹ lawọn eeyan maa gba kọja lọ si ibi ileegbe nla tuntun ti ijọba fẹ kọ,'' Ọgbẹni Adisa ṣalaye.
Ijọba Oloye Obafemi Awolowo lo ya ilẹ ti wọn kọ ileegbe naa si lori, ṣugbọn ijọba ologun labẹ alaṣẹ Col. David Jemibewon lo kọ ile naa.
Awọn gomina to ti jẹ tẹlẹ nipinlẹ Oyo ti gbiyanju lati lo ilẹ ti ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS wa lori rẹ. amọ igbesẹ naa ko kẹsẹ jari.