You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Police rescue: Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano ti doola ẹmi ọmọ ọdun marundinlogun kan ti awọn obi rẹ somọlẹ bii ẹran fun ọdun mẹwaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe lati igba ti Aisha Jubril ti wa ni ọmọ ọdun marun un ni wọn ti somọlẹ si inu ile.
Kọmisọnna ọlọpaa ni kete ti iroyin ipo ti ọmọ naa wa tẹ awọn leti ni awọn ọlọpaa ti sigun lọ sibẹ lati lọ doola ẹmi rẹ.
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- PDP borí ìdìbò káńsù ní Rivers, AAC, SDP fárígá
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
Awọn ọlọpaa ni irisi ọmọ naa fihan pe ko jẹun, bẹẹ si ni ko ri itọju to peye nitori ibi ti wọn ti mọlẹ si kun fun idọti.
Nibayii, Aisha ti wa ni ileewosan Murtala Mohammed nilu Kano, nibi to ti n gba itọju.
Bakan naa ni iya Aisha, Rabi Mohammed, ti wa ni panpẹ ọ̣lọpaa , ti baba rẹ si ti salọ.
Nkan bi ọdun to kọja ni iru iṣẹlẹ bayii peleke si ni ilu Kano, ti awọn alabojuto yoo ma a so ọmọ mọlẹ bi ẹran.
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Ṣé o fẹ́ lọ sí ọ̀run rere? Wo bí Naira Marley ṣe le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wọlé
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé
Amọ, iyalẹnu lo jẹ nitori awọn obi Aisha to da ẹjẹ le e lori ni o fi iya jẹ ẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti awọn si ti gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n risi iwa ọdaran, ti yoo si ṣeeṣe ki wọn fi oju ba ile ẹjọ.
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Láàrin Akeredolu àti Jegede, ta ni ilé ẹjọ́ yóò gbé ipò gómìnà fún lónìí?
- Àwọn Gomina ṣetán láti yọwọ́ kúrò nínú sísan owó oṣù àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ àti Adájọ́- Fayemi