You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọmọ Iyabọ Ojo rí bàbá wọn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́fà
Awọn ọmọ mejeeji ti gbaju gbaja osere tiata lobinrin, Iyabọ Ojo bi, eyiun Priscilla ati Festus ti bẹrẹ si ni sọ bi inu wọn ti dun to lati fi oju kan baba wọ̀n lẹyin ọdun mẹfa ti wọn ti foju-rinju kẹyin.
Awọn mejeeji naa, ti wọn lọ lo isinmi wọn ni orilẹ-ede Amẹrika lo se alabapin awọn aworan ti wọn ya pẹlu baba wọn nibẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, ipinya ti wa ninu igbeyawo iyawo Iyabọ Ojo lati ọjọ pipẹ, to si jẹ pe oun lo n da awọn ọmọ mejeeji naa tọ ni Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Loju opo ikansira ẹni Instagram, Festus Oladunjoye Ojo, fedel x, to jẹ ọmọkunrin Iyabọ Ojo ni "Baba mi ree, fun ẹyin ti ẹ fẹ mọ bi baba ti ri. Bi o tilẹ jẹ pe emi ko tii foju kan-an lati ọ̀dun mẹfa sẹyin, n se lo dabi ẹni pe ọsẹ diẹ sẹyin ni mo ti ri gbẹyin, nigba ti a foju kanra loni. Itan naa pọ̀ sugbọn mo gbadun ara mi loni."
Bakan naa ni eyi obinrin ni, Priscilla Ajọkẹ Ojo sọ loju opo Instagram rẹ, its priscy pe "Ẹyin eeyan, ẹ wo baba mi, a ko fi oju ri ara wa fun ọdun mẹfa, amọ inu mi dun lati jade pẹlu rẹ loni, lati dara pọ di ẹbi kan soso.
Iyabọ Ojo gan funra rẹ, to jẹ mama awọn ọmọ mejeeji yii, loju opo Instagram rẹ, iyaboojofespris, ni "Ẹ́ wo awọn ẹbi Ojo, awọn ọmọ baba wọn". Sugbọn Iyabọ ko ba wọn ya ninu fọto ti awọn mọ naa ba baba wọn ya.