India Cremation: Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun

Ọ̀tọ̀ ni ikú, ọ̀tọ̀ ni àìsàn , ẹni tí ọlọ́run kò bá kọ ikú mọ́ kò ní báwọn dé ọ̀rún alákeji, èyí ló dífá fún obìnrin kan tí àwọn ẹbí rẹ̀ rò pé ó tí kú lẹ́yin tó ní ààrùn coronavirus.

Lójijì tó ku ìṣẹ́jú pérété tí wọ́n yóò sin òkú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọ́n ni India níbiti wọ́n ti máa n sun òkú wọ́n di eérú, èyí ní wọ́n fẹ́ ṣe nígbà ti obìnrin náà lájú sáyé.

Ìròyin UK Express tó jáde lọ́jọ́ Iṣẹ́gun sọ pé Shakuntala Gaikwad, ẹni ọdún mẹ́rìndílọ́gọ́rin dédé lájú sáyé pẹ̀lú omi lójú bí àwọn ẹbi rẹ ṣe ti gba s\i inú pósí fún kí wọ́n to to igi ìdáná le lórí.

Sáájú ni ìyá àgbà náà ti ni ààrùn Covid-19 ti o si ya ara rẹ sọ́tọ̀ nínú ilé ni abúlé Mudhale ni ìpínlẹ̀ Maharashra India. Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù Kaarun ipò àìlera rẹ̀ burú síi ti àwọn ẹbi rl sì sáré gbe lọ si ilé ìwòsàn.

Gbogbo igbokegbodo ẹbi náà wan ni ko sí bẹ́ẹ̀dì ni àwọn ilé ìwòsànn ti wan gbé lọ, nágbà ti wan ń dúró nínú ọkọ̀, lo dáku gbọgandan, gbogbo ìgbìyànjú ẹ̀bí rẹ̀ láti jí pàda ló já sí pàbó.

Èyí ló mú kí ẹbi rẹ̀ rò pé ó ti kú, wọ́n sì da padà sílé láti lọ bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú rẹ̀, àwọn ẹbi kéde fún àwọn mọ̀lẹ́bí tó kù, wọ́n si kéde àsìkò ìsìkú rẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn

Súgbọ́n bí ó ṣe ku ìṣẹ́jú pérété tí tí wọ́n yóò ṣáná sí àwọn igi tí wọ́n ti kò fún sísun rẹ̀ ló bá lajú, ìyàlẹ́nu sì ló jẹ́ fún pe ó bá àra rẹ̀ níbí tí wọ́n ti fẹ́ dána sun.

Àwọn ẹbi rl tún sáré gbe padà sí ilé ìwòsàn nibi ti ó ti n gba ìtọ́jú.

Orílẹ̀-èdè India ni ààrùn coronavirus fi se ibugbe báyìí tí ó sí lé ní ènìyàn mẹ́rìnlélogojì tó ti lùgbàdì ààrùn Covid 19, ti ènìyàn tó din díẹ̀ ni ọ̀ọ́dúrún ẹgbẹ̀rún to bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.