You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kemi Afolabi: Mo mọ rírì àwọn olólùfẹ́ mi, àdúrà ti wọn náà yóò gbà
Gbajugbaja osere lobinrin nni, Kẹmi Afọlabi ti fi fọnran aworan kan ransẹ lati ilu Meccah eyi to fi n fi ẹmi imoore rẹ han si awọn ọmọ Naijiria ti wọn gbarata lasiko to wa lori idubulẹ aisan nilu Meccah.
Kẹmi, loju opo ikanni Twitter rẹ lọjọ Ẹti, mọriri gbogbo ọmọ Naijiria nile ati lẹyin odi ti wọn n rọjo adura si nigba ti aarẹ n se, to si n gbadura pe wọn ko ni fi iru rẹ gba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Pásítọ̀ ọmọ Nàìjíríà, Omotoso, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kàn pàdánù ìwé ìgbélùú ní South Africa
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ kọ ìyà tí wọ́n fi ń jẹ yín lórí owó oṣù tuntun - Oshiomole gbarata
- Àwọn Pásítọ́ ijọ Redeem márùn ún bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé ní Ijebu Ode
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
- Aáwọ̀ ọ̀dọ́ Yorùbá àti Hausa ló dá wàhálà sílẹ̀ ní Ṣásá - Ṣeriki Hausa
Osere tiata naa, ti oju rẹ ti gun rege pada ni "Mo fẹ lo akoko yii lati dupẹ pupọ lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun ifẹ, adura ati igbarata wọn lasiko ti mo fi ni iba, ori mi wu fun iru ifẹ ti ẹ fi han si mi. Ara mi ya bayii, ti ara mi si ti mokun pada, irinajo ibi lo lagbara pupọ amọ o yẹ lati see, gẹgẹ bi Oluwa ti kọ wa pe irin ajo irapada ko rọrun rara."
Kẹmi Afọlabi to gbadura naa ni Kabbah, nibi ti adura ti maa n gba, wa se ladura pe Ọlọrun yoo gbọ adura awọn ololufẹ oun.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni BBC Yoruba mu iroyin wa fun yin pe ara osere tiata naa ko ya lasiko to fi lọ fun eto Hajj nilu Mecca, ti ọpọ ọmọ Naijiria si n gbadura fun ajinde ara rẹ.