500 Teeth: Àgbọ̀n ọmọ náà tó wú làwọn obi rẹ̀ gbe lọ sí ilé ìwòsàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni itan ọmọdekunrin kan ti awọn dokita yọ eyin to le ni ẹẹdẹgbẹta ni agbọn rẹ.

Ọmọdekunrin naa, tii se ọmọ ọdun meje ni awọn obi rẹ kofiri pe agbọn isalẹ rẹ n wu, eyi to mu ki wọn gbe lọ sile iwosan.

Lẹyin ayẹwo finnifinni, awọn dokita to wa nile iwosan kan nilu Chennai lorilẹede India, sawari pe ọpọ eyin lo wa nisalẹ agbọn to wu naa, ti wọn si pinnu lati se isẹ abẹ fun-un.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin isẹ abẹ oni wakati marun-un, ni wọn yọ eyin to le ni ẹẹdẹgbẹta ni agbọn rẹ.

Dokita Pratipha Ramani, tii se olori ẹka to wa itọju eyin nile iwosan naa salaye pe, lati igba ti ọmọde naa ti wa lọmọ ọdun mẹta, ni wọn ti se akiyesi pe agbọn rẹ naa wu amọ wọn fi silẹ nitori pe ko fọwọsowọpọ pẹlu wọn.

Lootọ ni awọn eyin naa tobi ju ara wọn lọ, amọ gbogbo wọn lo jọ eyin, ti wọn si ni ki ọmọ naa maa lọ sile lẹyin ọjọ kẹta to se isẹ abẹ naa.

Fidio bi wọn se yọ eyin naa ree:

Awọn dokita onisẹ abẹ marun ati awọn onimọ nipa ẹjẹ meje lo sisẹ lasiko isẹ abẹ naa, ki wọn to ri awọn ọpọ eyin naa yọ, bẹẹ si ni ijọba lo sanwo isegun ọmọdekunrin ọhun.