You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Slave Trade: Olórí ilé aṣòfin Amẹrika lọ Ghana láti bẹ ilé wò fún ayẹyẹ irinwó ọdún òwò ẹrú
Lọdun 1619, ọkọ oju omi kan fidi kalẹ si ibudo kan to jẹ ti ilẹ Gẹẹsi, eyi ti wọn n pa ni Virginia, to wa lorilẹede Amẹrika bayii, to si ko ogun ọmọ ilẹ adulawọ sinu rẹ.
Igbesẹ yii ni igba akọkọ ti yoo wa ni akọsilẹ pe awọn ẹru to jẹ adulawọ de si agbegbe naa eyi to wa di ara orilẹede Amẹrika bayii.
Awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi to n paraaro oju omi lo fi tipa gba ọkọ oju omi to jẹ tawọn eebo Pọtugi naa lori okun Mexico.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọkọ oju omi yii si lo gbe awọn ọmọ adulawọ to to ọọdunrun ati aabọ (350), ti wọn ko lati orilẹede Angola, ọpọ wọn lo ti ku lasiko irinajo naa nitori ipo inilara ti wọn la kọja.
Awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi to gba wọn loju okun naa si lo ta awọn adulawọ ọhun fawọn amunisin to wa ni Virginia.
Amọ ariyanjiyan ti n waye lori ohun to n sẹlẹ si awọn ẹru naa ni kete ti wọn ba ti ta wọn lẹru tan. Lẹyin eyi si ni akọsilẹ wa pe owo ẹru ati iwa ẹlẹyamẹya bẹrẹ nigba ti iye awọn adulawọ to n wọ orilẹede Amẹrika n pọ si.
Se awọn ẹru yii ni akọkọ ti yoo gunlẹ si orilẹede Amẹrika bi?
Awọn akọsẹmọsẹ kan ti wa woye pe pataki isẹlẹ to waye lọdun 1619 naa ko see foju fo nitori wọn ti n lo awọn adulawọ to wọ ni Amẹrika naa lati sisẹ ni oko taba ni agbegbe Bermuda, eyi ti ilẹ Gẹẹsi n dari.
Bakan naa, lawọn eebo pọtugi ti n ko awọn ẹru lọ si agbegbe wọn lati saa onka sẹnturi kẹẹdogun (15th century)
Bawo ni wọn se fẹ sami irinwo ọdun ti owo ẹru bẹrẹ?
Ile asofin apapọ nilẹ Amẹrika ti se agbekalẹ ajọ kan ti yoo ri si akoso awọn eto to n sami irinwo ọdun itan awọn ọmọ Amẹrika to jẹ adulawọ ( African-American) ti yoo waye lọdun yii.
Olori ile asofin kekere nilẹ Amẹrika, Nancy Pelosi si ti rinrin ajo lọ si orilẹede Ghana fun ayẹyẹ irinajo irinwo ọdun ti awọn ẹru akọkọ to jẹ adulawọ gunlẹ si orilẹede Amẹrika.
Lara awọn asofin to kọwọrin pẹlu Pelosi ni awọn agba asofin to jẹ adulawọ.
Orilẹede Ghana si ti kede ọdun ta wa yii, 2019, gẹgẹ bii ọdun ipadabọwale, pẹlu awọn oniruuru eto ti wọn gbe kalẹ, eyi to wa lati se iwuri fun awọn ọmọ ti orirun wọn jẹ Afirika, lati wa se abẹwo si Afirika, ki wọn si wa tẹdo sile.
Aarẹ Donald Trump ẹwẹ naa wa nilu Jamestown nipinlẹ Virginia lọsẹ yii lati bawọn sami irinwo ọdun ti ijọba awa ara wa lati ipasẹ awọn asoju bẹrẹ lagbegbe naa.
Sugbọn ko sọ ninu ọrọ apilẹkọ rẹ pe o ti pe irinwo ọdun ti awọn ẹru akọkọ to jẹ adulawọ kalẹ si Virginia.