Oshiomole: Ẹ pe aṣaájú olóṣèlú níjà láti lo ọrọ̀ ìpínlẹ̀ fún àìní òṣìṣẹ́

Alaga apapọ fun ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Adams Oshiomole, ti kesi awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorilẹede Naijiria lati maa pe awọn asaaju oloselu nija lọna ati ri daju pe wọn lo ọrọ ati ohun alumọni ipinlẹ wọn lati ba aini awọn osisẹ pade.

Oshiomole pe ipe yii nilu Abuja nibi apejẹ kan ti wọn fi n bu ọla fun oludari agba fun ajọ to n risi ọrọ osisẹ lagbaye, ILO, ọgbẹni Guy Ryder.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oshiomole, lasiko to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, wa gbarata lori iha ti awọn asaaju oloselu n hu loju ọna mimu agbega ba awọn osisẹ Nigeria, pẹlu afikun pe, awọn ẹgbẹ osisẹ yii gbọdọ mu ọwọ to le lati mu ayipada ba ipo ti wọn wa.

"A gbọdọ lo ọna to yatọ bayii nipa sisan owo osu to kere julọ nitori gbogbo owo ọja lo ti lọ soke lai si afikun fun owo osu awọn osisẹ, ti ohun gbogbo si wa loju kan soso."

Oshiomole tun tẹsiwaju pe, "ti mo ba n sọrọ gẹgẹ bii ẹni to rinu rode nipa ọrọ ẹgbẹ osisẹ, o da mi loju pe awọn ẹgbẹ osisẹ ko kan lee wa lasan amọ wọn gbọdọ ni apọn lati lo gbogbo agbara wọn lai boju wẹyin."

O wa rọ awọn olori ẹgbẹ osisẹ lati si ri daju pe wọn lo awọn ọrọ ipinlẹ wọn fun anfaani awọn osisẹ ati mọlẹbi wọn.