Sasa Market: Seriki Hausa ní ogún èèyàn ló farapa nínú ìjà Ṣasa

Seriki Sasa, tii se olori ẹya Hausa to wa lagbegbe Sasa nilu Ibadan Alhaji Haruna Mai Yasin ti salaye ohun to sokunfa ija to bẹ silẹ lsja Sasa eyi to mu ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ọja naa pa.

Gẹgẹ bi Yasin ti wi, o ti to ọsẹ kan bayii ti awọn janduku to jẹ ẹya Hausa ati Yoruba ti n san ọna wahala naa ninu ọja ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yasin ni "A kan ro pe awuyewuye ati aigbọra ẹniye lasan to maa n waye ni, sugbọn laarọ yii ni awọn ọdọ Hausa ati Yoruba bẹrẹ ija eyi to mu ki wọn ba ọpọ ọja jẹ nibẹ, tawọn eroja ounjẹ si bajẹ pupọ, bẹẹ ni o to ogun eeyan to fara pa yannayanna.

Yasin fikun pe, wọn ti gbe awọn eeyan to farapa naa lọ sile iwosan fun itọju.

Ẹwẹ, awọn osisẹ agbofinro ti gba akoso ọja naa, ti wọn si ti n pese eto aabo to yẹ sibẹ.

Ìjọba Ọyọ ti ọjà Ṣáṣá pa ní Ibadan torí ìjà láàrin ẹ̀yà Hausa

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti paṣẹ wi pe ki awọn agbofinro sọ agadagodo si ẹnu ọna abawọle ọjọ Ṣaṣa to n bẹ ni agbegbe Moniya niluu Ibadan nitori rogbodiyan to bẹ silẹ laarin awọn ẹya Hausa to n taja nibẹ lọjọ Ẹti.Ko fi bẹẹ si ẹnikan to mọ eredi ti ija fi bẹ silẹ ni ọja naa, titi di asiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii.

Alakoso ọja naa, Haruna Mai Yasin to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ikọ iroyin BBC Yoruba ṣalaye pe, ṣadede ni wọn rii wi pe awọn Hausa kan to jẹ ontaja ninu ọja naa n ba ara wọn ja debi pe, awọn kan fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa.

A tọpinpin awọn ti wọn fi ara pa lọ si ile Iwosan Al-Salam to n bẹ ni agbegbe Mọniya, lati ti fi ọrọ wa wọn lẹnu wo lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn ọlọpaa to duro wamuwamu si ẹnu ọna ile iwosan naa ko jẹ ki ẹnikẹni wọle sibẹ.

Ninu atẹjiṣẹ ti alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi fi ṣọwọ si ikọ iroyin BBC Yoruba, o fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, bakan naa lo ṣe alaye wi pe eeyan mẹsan lo fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju wi pe, awọn afurasi mẹsan ọtọọtọ ni awọn ọlọpaa ti nawọ gan, wọn si ti gbe mẹta ninu wọn lọ si ile ẹjọ.

Lọwọlọwọ bayii, alafia ti jọba lọja naa ati agbegbe rẹ.