You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bamise BRT bus Court case: Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ tí dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ BRT tí Bamise wọ ti jẹ́jọ́ rèé
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn ti péjú sí ilé ẹjọ́ Majisireeti Yaba fun igbẹjọ iku Bamise Ayanwole.
Akroyin BBC Yoruba to wa nibẹ fi awọn aworan ranṣẹ to n ṣafihan bi wọn ṣe ko ṣẹkẹṣẹkẹ si dẹrẹ́ba naa, Andrew Nice lọwọ ti wọn n gbe e lọ si ile ẹjọ̀.
Ni ile ẹjọ Majisireeti to wa ni agbegbe Yaba ni ipinlẹ Eko ni igbẹjọ naa ti waye.
Bi awọn oniroyin to wa nib ṣe woye, o jọ pe ni kete ti dẹrẹba naa de ile ẹjọ ni wọn ti dari rẹ lọ si ibi ti awọn eeyan to mọ pe wọn ti baba lọ si inu ile jọ ni.
Akroyin BBC Yoruba to wa nibẹ fi to wa leti pe adajọ ti dajọ pe ki wọn gbe dẹrẹba naa lọ ẹwọn Kirikiri pe ibẹ ni yoo wa titi gbogbo asiko ti wọn yoo maa da ẹjọ rẹ.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.