Kemi Afolabi: Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oṣerebinrin, Kemi Afolabi ti sọ iriri rẹ lọwọ awọn adigunjale to kọlu u lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2022.

Eyi waye lẹyin ọjọ diẹ to kede sita pe aisan kan ti ko gboogun n ba oun finra.

Aisan naa mu ko ta ọpọlọpọ dukia rẹ lasiko to fi wa ni ileewosan fun oṣu mẹta gbako.

Ninu ọrọ to kọ si ori Instagram rẹ, Arabinrin Kemi Afolabi sọ pe lasiko ti oun n pada si ile lẹyin to ya sinima tan ni agbegbe Arepo nipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni lasiko ti ọkọ̀ oun wa ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni awọn adigunjale ọhun kọlu ọkọ oun.

O ni wọn fi nkan fọ gilaasi iwaju ọkọ, ti erunrun gilaasi naa si ya oun ni gbogbo ara.

Yatọ si eyi, o ni wọn tun fi àdá ge oun ni apá. Wọn gba foonu, ati dukia ki wọn o to salọ.

Bakan naa ni Arabinrin Afolabi sọ pe wọn tun fi àdá ṣá awakọ oun ni ori.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ko ti i fi oju kan orun lati igba ti iṣẹlẹ naa waye nitori ipaya ati iporuru ọkan.

Oṣerebinrin naa ni o ṣeni laanu pe awọn alaṣẹ ijọba kii gbọ ẹkun araalu botiwu ki wọn o pariwo to.

Ṣugbọn ṣa, o ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ju bẹẹ lọ.