Abiola Ajimobi: Bàbá mi jẹ́ aránsọ, ìyá mi sì jẹ́ ọlọ́jà wóróbo

Gomina ipinlẹ Ọyo, Abiola Ajimobi ti parọwa si awọn ọdọ wi pe ibi ti eniyan ti dide ko gbọdọ jẹ idiwọ tabi idena si atigoke agba.

Ajimobi sọ eyi lasiko to n ba awọn ọdọ sọrọ nibi ipade Young African Leaders Initiative fun awọn olokowo kekeeke lorilẹede Naijiria.

O ni ọmọ atapata dide ni oun bi ọpọ ọmọ Naijiria, ti baba oun si jẹ aransọ, nigba ti iya oun jẹ ọlọja. Amọ oun ko jẹ ki ipinlẹsẹ oun dina atigoke nitori naa ni oun se tẹra mọsẹ.

Nigba ti oun ba awọn ọdọ naa sọrọ, gomina tẹlẹri naa ni awọn eniyan nilo lati ma a ni ero rere, ki ilọsiwaju to jọju le de ba aye awọn eniyan.

Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri naa wa rọ awọn ọdọ lati fi ọkan si oun gbogbo ti wọn ba n se, ki itẹsiwaju le ba ọrọ aje wọn.