You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Funke Akindele Nollywood: Mi ò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn! Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ mi lé!
JJCSkills to jẹ ọkọ gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba to tun jẹ adẹrinpoṣonu, funke Akindele ti gbogbo eniyan mọ si Jenifa ṣe oun iwuri nla fun ololufẹ rẹ.
"Isẹ ọpọlọ rẹ maa n da wa lọrun gan, o maa n ṣe ọkan wa pẹlẹ". Lara orin ti awọn olorin kan fi ṣapejuwe patakii Funke Akindele si wọn ree.
Funke Akindele ti di ìyábejì ni ọdun melo kan sẹyin.
Kaakiri agbaye ni wọn ti mọ Funke gẹgẹ bii gbajugbaja apanilẹrin laarin awọn oṣere fiimu Yoruba ati ti ede oyinbo koda to fi mọ awọn toke okun kọọkan.
Ko si ani ani pe akọkọ lo jẹ loju ewe awọn apanilẹrin to dantọ ju fun awọn kan.
Fọfọ ni oju opo ayelujara rẹ kun fun oriṣiriṣi ikini latọdọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ, awọn olorin to jẹ ọrẹ rẹ, awọn oṣiṣẹ rẹ koda to fi mọ awọn aladugbo rẹ nibi to n gbe.
Ṣe ni Funke Akindele funrarẹ ṣe ajọyọ pẹlu awọn ololufẹ rẹ pẹlu fidio bo ṣe n ṣe idupẹ lọwọlọwọ ninu ile rẹ tawọn eeyan si n ri i wo loju opo instagram rẹ ti wọn si n fi ọrọ ikini ranṣẹ si i.
Ninu fidio naa lo ti tẹle ofin ijinasiraẹni gẹgẹ bi ko ṣe pe ero ayafi awọn perete ta n gbọ ohun wọn labẹlẹ ati olorin kan to pe ti a ri ninu fidio naa to n kọrin yin Ọlọrun logo nitorii Funke Akindele.
Eyi gaan lo pe ni ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lẹyin eyi to gba foonu lọwọ ẹni to n ṣafihan rẹ to si ṣe adura pupọ fun awọn ololufẹ rẹ pẹlu ede to maa n fi ṣe ere awada rẹ bii ẹni ti ede gẹẹsi ko dan mọnran rara lẹnu rẹ.