You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mummy calm down: Oreoluwa di 'Ambassador' ilésṣẹ́ tó ń ṣòwò ilẹ̀ àti ilé
Ileeṣẹ kan ni ilu Abuja ti yan Oreofeoluwa Lawal-Babalola, ti ọpọ eeyan mọ si "Mummy calm down" gẹgẹ bi aṣoju rẹ.
Oreoluwa tọwọ bọwe adehun ọlọdun meji pẹlu ileeṣẹ naa to n ṣowo ilẹ ati ile, ni olu ileeṣẹ rẹ to wa ni Abuja.
Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn tọwọ bọwe adehun tan, alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ ọhun, Ọgbẹni Akintayo Adaralegbe ni ọkan Akin ti Oreofeoluwa ṣe nigba ti iya rẹ fẹ da seria fun un lo jẹ ki ileeṣẹ naa nifẹ si i.
- 'Mo lè fọwọ̀ sọ̀yà fún yín pé Sunday Shodipe ti wà láhàmọ́ wa - Alukoro Ọlọ́pàá Oyo
- Ọkùnrin tó dàgbà jù lágbàyé jáde láyé lẹ́ni ọdún 116
- Nigeria Police Recruitment 2020: Àwọn ohun tí ẹ nílò fún àyẹ̀wò ìgbanisíṣẹ́ ọlọ́pàá tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Mon, Aug 24
- 'Ẹ̀pa ò bóró mọ́! Òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó sí kàǹga ní Ipaja ni wọ́n yọ'
O ni "bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo wo fido naa ti wọn si n rẹrin, ṣugbọn ọgbọn ti mo kọ ninu rẹ ko kere rara."
Adaralegbe ṣalaye pe "Ọmọdekunrin naa jẹ akinkanju; ohun to ṣe naa ṣi n jẹ ko ye gbogbo wa pe ninu gbogbo iṣoro ti a ba n dojukọ nile aye, o yẹ ka maa ni suuru."
O ni ileeṣẹ naa pinnu lati ba ọmọdekunrin ọhun dowo pọ nitori o ni igboya, o si mọ bi eeyan ṣe le yọ ara rẹ kuro ninu iṣoro.
Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ naa ni awọn gbajugbaja oṣere tiata Yoruba bii Femi Adebayo, Tayo Odueke ti ọpọ mọ si Sikira Sindodo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni Ayo Ajewole ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Wolii Agba wa nibẹ, pẹlu Sule Alao Malaika, Keji Osundara atawọn eeyan gbajumọ miran.
Oreofeoluwa di gbajumọ lẹyin ti fidio kan fa ori ayelujara ya, nibi to ti n bẹ iya rẹ to fẹ na a lẹyin to ṣaṣemaṣe kan, to si n logun "mummy calm down."
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Mummy calm down video: Oreoluwa fẹ́ di 'Ambassador'
Gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Yinka Ayefele ti ke gbajare lori ayelujara pe ki awọn eeyan ba oun wa nọmba ipe Oreoluwa.
Oreoluwa lo di ilumọọka bayii lẹyin ti fidio kan lu awọn oju opo ayelujara pa ninu eyi to ti n sọ fun iya rẹ pe ko 'Calm Down' lasiko to fẹ na a.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọlọ́pàá sálọ fún aráàlú l‘Okeho, nígbà tí wọn yari láti ṣun olè méjì tó kù
- Kí ìjọ mi ní Sagamu le gbòòrò ni mo fi ń ṣiṣẹ́ ajínigbé pawó - Pásítọ̀
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
- "Ọmọ mi kò tíì mọ̀ pé òun ti di ìlúmọ̀ọ́ká, ó ń wádìí bó ṣe ń rí ara rẹ̀ lórí ayélujára"
- Boko Haram da ìbọn bo ọkọ̀ gómìnà Borno, ẹ̀ṣọ́ àláàbò rẹ̀ farapa
Nigba to n kede eyi loju opo Instagram rẹ, Ayefele ni inu oun dun pe iya ọmọde naa ti 'Calm Down' bayii, ti oun si n ke si ẹnikẹni to ba mọ nọmba obi ọmọde naa, lati fi ransẹ si oun.
Bi o tilẹ jẹ pe Ayefele ko salaye idi to fi fẹ kan si awọn obi Oreoluwa, amọ ọpọ eeyan to fesi si ikede naa ni, oriire nla ni ọmọde naa se.
Bi o ba se n lọ nipa ọrọ yii, a tun mu wa fun yin.
Oreoluwa ninu fidio Mummy Calm Down fẹ́ di 'Ambassador'
Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe, Yoruba ni kirakita ko mọla, ka sisẹ bi ẹru ko da nnkankan, Ọba Oluwa nii gbe ni ga.
Bẹẹ ni ọrọ ri bayii fun ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrin Oreoluwa Lawal-Babalola, to n sọ fun iya rẹ pe, ko 'calm down' lasiko to fẹ na a.
Lọwọ lọwọ bayii, ajọ kan ti kii se tijọba, to n gbogun ti iwa ipa ati ifiyajẹni ninu idile, ti fẹ yan ọmọ naa ni asoju ajọ naa, ti wọn n pe ni Ambassador.
Ko tan sibẹ o, ajọ naa tun ti gba lati maa lo ọrọ 'Calm Down' gẹgẹ bii ọrọ akọmọna lati maa pẹtu si aawọ.
Ajọ naa ni ti gbogbo agbaye ba le e maa fara balẹ, tii se calm down, gbogbo iwa ipa to n sẹlẹ lagbaye ni yoo dopin.
Ikede kan ti aarẹ ajọ alaanu naa, Oloye Dozie Kaidi Obiaku se loju opo Instagram rẹ, lo sisọ loju ọrọ naa, to si ni Oreoluwa ko ni se asoju ajọ naa lọfẹ, wọn yoo tun fi owo osu tii nidi fun-un.
Ni kete ti fidio ti ọmọ naa ti n bẹ iya rẹ pe ko calm down n ja rainrain lori ayelujara, ni ajọ naa ti fi ikede sita pe, wọn n wa ọmọde naa, lati wa se asoju ajọ ọhun.
Obiaku fikun pe, igbimọ oludari ajọ to n gbogun ti iwa ipa ninu ile ti n jiroro lori bi asoju awọn naa, Oreoluwa, yoo se maa waasu fun awọn eeyan, lati maa fi ara balẹ, tii calm Down.
BBC Yoruba yoo kan si awọn obi rẹ lai pẹ lati mọ boya wọn ti fi ọwọ si pe ki ọmọ wọn di asoju ajọ ọhun, ta si mu abọ wa fun yin.
"Ọmọ mi kò tíì mọ̀ pé òun ti di ìlúmọ̀ọ́ká, ó ń wádìí bó ṣe ń rí ara rẹ̀ lórí ayélujára"
Iya ọmọdekunrin ti fidio rẹ tan kari ayelujara tun ti sọ awọn ohun miran nipa ọmọ rẹ ti orukọ rẹ njẹ, Oreofeoluwa Lawal-Babalola.
Iya rẹ, Abilekọ Babalọla lasiko to n ba BBC YORUBA sọrọ ni, ọmọ ọdun mẹrin ni ọmọ oun.
Abilekọ Babalọla ni ọmọ oun jẹ ọmọ to ma n mu inu oun dun nigba gbogbo nitori o ma n pa oun lẹrin pẹlu iṣesi rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
- Akẹ́kọ̀ọ́ Babcock tí wọn bá lòpọ̀ nínú fídíò rí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní fásitì òkè òkun
- Aláwàdà ni ọmọ mi láti kékeré, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbé mi mọ́ra- ìyá ‘Mummy calm down’ (Toluige Olokoobi Babalola)
- Wo ìyàtọ̀ tó wà láàrin Bíbélì Yorùbá tí Kumuyi kọ sí èyí tó wà ńlẹ̀
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ, ìkókó mẹ́jọ kú nílé ìwòsàn lálẹ́ ọjọ́ kàn
- Dayo Amusa gbarata lórí bí agbófinró ṣe ń pa ọ̀dọ́ láì nídìí
Bakan naa lo ni ọmọ oun kii fi ero rẹ pamọ, o ma n sọ bi o ba ṣe ri ni ọkan rẹ ni.
O fikun pe iwuwasi ọmọ oun ati bi o ṣe n pegede si ni ileewe fihan pe ọlọpọlọ pipe ni ọmọ oun.
Abileko Babalola ni oun ko lero pe fidio naa le tan kaakiri ayelujara bi eleyii.
O ni igba ti oun kọkọ rii to n ja rain lori ẹrọ ayelujara, ẹru kọkọ ba oun, amọ oun ti faramọ ilumọọka ti fidio naa ti jẹ ki awọn da bayii.
Nipa ti Oreofeoluwa Lawal-Babalola, iya rẹ ni ko i tii mọ nkankan nipa ohun ti fidio naa da silẹ, amọ oun to sọ fun iya rẹ ni wi pe 'Mummy, mo n ri ara mi ri lori ẹrọ ayelujara kaakiri'.
Abilekọ Babalọla ni gbogbo igba ti oun ba ti fẹ fi iya jẹ ọmọ naa nitori o ṣe aṣemaṣe ni ọmọ naa ma n dapara, ti oun ko si ni lee naa mọ.
Aláwàdà ni ọmọ mi láti kékeré, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbé mi mọ́ra- ìyá 'Mummy calm down' (Toluige Olokoobi Babalola)
Iya ọmọdekunrin to wa ninu fidio kan ti ọpọ eeyan mọ si "Mummy calm down," Toluige Olokoobi Babalola ti sọ pe ọmọ naa maa n pa oun lẹrin ṣaaju iṣẹlẹ to sọ ọmọ rẹ di gbajumọ.
Babalola lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu akọroyin ileeṣẹ BBC Yoruba.
Ọmọdekunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Oreoluwa di gbajumọ lẹyin ti fidio ibi to ti n bẹ iya rẹ pe ko fara balẹ nigba to fẹ na an lẹyin to ṣe aṣiṣe kan ti ko mẹnuba jade sori ayelujara.
Ni bayii, Babalola ti ṣi oju opo Instagram fun Oreoluwa lẹyin ti fidio "Mummy calm down" naa sọ ọ di gbajumọ tan.
Ogunlọgọ eeyan lo ti wo fidio ọhun, lẹyin to jade lori ayeluhara, koda gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu gan ko gbẹyin.
Lẹyin to wo fidio ọhun tan, Sanwo-Olu sọ ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ pe oun yoo nifẹ lati foju-rinju pẹlu ọmọ ọhun.
Lẹyin naa lo parọwa si awọn olugbe ipinlẹ Eko lati "Calm down" lasiko pọpọṣinṣin ọdun leya.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Sanwo-Olu náà wá sọ fáwọn ará Eko pé kí wọn 'Calm Down'
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe, oun yoo ṣepade pẹlu ọmọ ọkunrin to ni ki iya oun farabalẹ nigba to fẹ na a lẹgba.
Sanwo-Olu lo sọ ọrọ naa loju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe ara oun bu maṣọ lẹyin ti oun wo fidio ọmọdekunrin naa tan.
O ni "Itakurọsọ laarin ọmọ naa ati iya rẹ panilẹrin, ṣugbọn o sọ nipa akitiyan awọn obi lati kọ awọn ọmọ wọn lẹkọọ ile to ye kooro."
- Mamman Daura rí ìjà ọmọ Nàíjíríà torí ó pè fún wíwọ́gilé pínpín ipò ààrẹ lẹ́lẹ́kùn jẹkùn
- Ìkúnlẹ̀ abiyamọ, ìkókó mẹ́jọ kú nílé ìwòsàn lálẹ́ ọjọ́ kàn
- Dayo Amusa gbarata lórí bí agbófinró ṣe ń pa ọ̀dọ́ láì nídìí
- Ẹyìn tí Hydroxychloroquine, Zinc ati Zithromax da lára yá,ẹ bọ síta wà jẹrìí mí-Dr Stella Emmanuel
Gomina ọhun ni ki awọn olugbe ipinlẹ Eko farabalẹ nitori ajakalẹ arun Coronavirus ṣi n ba gbogbo agbaye finra.
Lẹyin naa ni Sanwo-Olu parọwa si awọn eeyan ọhun lati "Calm down" paapaa lasiko ọdun Ileya to wole de wẹrẹ.
Ọmọ ọkunrin ọhun di gbajumọ lẹyin ti fidio ibi to ti n bẹ iya rẹ pe ko farabalẹ lẹyin to ṣaṣemaṣe kan ti ẹnikẹni ko mọ jade lori ayelujara.
- Ẹyìn tí Hydroxychloroquine, Zinc ati Zithromax da lára yá,ẹ bọ síta wà jẹrìí mí-Dr Stella Emmanuel
- Ọ̀pọ̀ òkú ṣùn, dúkìá jóná nínú àkọ̀tun ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù gáàsì l‘Eko
- Tí ìjọba kó bá dẹ́kun ìpànìyàn ní Gúúṣù Kaduna, aráàlú yóò jà fúnra wọn - CAN
- Ayẹyẹ ìgbaniwọlé sínú ẹgbẹ́ òkùnkùn bẹ́yìn yọ, wọ́n lu ọmọ ẹgbẹ́ tuntun pa
Ninu fidio naa, iya rẹ gbiyanju lati na a lẹgba, ṣugbọn ni ṣe lo n pariwo "Mummy calm down, mummy calm down" lọna ati bọ lọwọ ijiya ọhun.
Ko pẹ ti fidio naa jade to fa oju ayelujara ya, ọpọ eeyan lo ti pin fidio naa kaakiri ni Naijiria ati loke okun.
Gomina Sanwo-Olu pari ọrọ rẹ pe oun yoo nifẹ lati foju ganni ọmọdekunrin naa laipẹ