You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mamman Daura: Ọmọ Nàíjíríà ní ọgbọ́n àti gbé ààrẹ fún ẹ̀kùn àríwá ni
Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori ayelujara nipa ohun ti ọrẹ timọ-timọ aarẹ Buhari, Mamman Daura sọ.
Ọjọ Isẹgun ni Daura kede pe, ẹni to ba kunju iwọn lo yẹ ko jẹ aarẹ Naijiria, kii ṣe nipa pinpin ipo aarẹ ni ẹlẹkunjẹkun.
Mamman Daura lọ sọ ọrọ yii lasiko to n kopa lori ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC.
- Oronpoto Animation: Akin Alabi ní kò dára bí eré aláwòrán fáwọn ọmọdé ṣe jẹ́ aláwọ̀ funfun
- Ẹyìn tí Hydroxychloroquine, Zinc ati Zithromax da lára yá,ẹ bọ síta wà jẹrìí mí-Dr Stella Emmanuel
- Ọ̀pọ̀ òkú ṣùn, dúkìá jóná nínú àkọ̀tun ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù gáàsì l‘Eko
- Tí ìjọba kó bá dẹ́kun ìpànìyàn ní Gúúṣù Kaduna, aráàlú yóò jà fúnra wọn - CAN
Daura ni ọpọlọpọ eniyan n sapejuwe bii ọkan lara awọn to lagbara ju ninu iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari.
Daura ni ẹni to ba kunju iwọn julọ ni wọn gbọdọ gbe ijọba fun ni ọdun 2023, wọn ko gbọdọ fi ṣe ọrọ ẹkun mi lo kan.
Amọ, awọn eniyan ti bẹrẹ si ni fesi loju opo Twitter pe, ọna ati ọgbọn lati jẹ ki ẹya Hausa nikan ma a ṣe ijọba lorilẹede Naijiria ni wọn n wa.
Bakan naa ni awọn kan ni ko tọ si Mamman Daura lẹnu lati sọ iru ọrọ bẹẹ fun awọn ọmọ Naijiria.
Amọ awọn miran faramọ ọrọ ti o sọ, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ko ri ọkan rẹ ati idi ti o fi sọrọ naa.
Awọn miran tilẹ gboriyin fun Mamman Daura wipe, otitọ ọrọ lo sọ nitori sise ipo aarẹ ni ẹlẹkunjẹkun ti sakoba fun wọn, ti ko si mu idagbasoke dani.
Ẹgbẹ afẹnifẹre naa wa lara awọn to bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Mamman Daura sọ, wọn ni bi wọn ṣe n pin ka laarin Ariwa ati Guusu naa ni ko se ma a lọ.