You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lisa Hanna: Ojú kìí rí arẹwà kó má kí i. Wo arẹwà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ kó di àárẹ wọn
Oju awọn ọmọ Naijiria ti ri arẹwa, wọn si ti ni awọn o kọ lati yan sipo aarẹ.
Ta ni arabinrin naa ti pe bawo ni ọrọ yoo jẹ ipo aarẹ ti ṣe waye?
Ni nkan bi ọsẹ meji sẹyin awọn ọmọ Naijiria ko mọ ẹni ti Lisa Hanna jẹ.
Amọ ọrọ ti yi pada lẹyin ti wọn ri fọnran fidio kan to ṣafihan arabinrin naa gẹgẹ bi oludije ipo aarẹ ni Jamaica.
Hmmm... Aṣiri ọrọ yi ti tu si wa lọwọ tori naa la ṣe fẹ sọ fun yin laisiyemeji pe arabinrin yi kii ṣe oludije ipo aarẹ
Ki lo wa mu atotonu wa?
Ko daju idi tawọn to fi fidio yi sita ti ṣe pe ni oludije ipo aarẹ ṣugbọn ohun ti fọnran wa fun ni pe wọn fi ṣe igbelaruge iṣẹ rẹ gẹgẹ bi aṣofin nilẹ Jamaica ati iṣẹ ribiribi to n ṣe.
Fọnran fidio taa n wi yi, o le ni eeyan miliọnu kan ti wo.
Gbopgbo ohun to wa ninu rẹ ko si kọja iṣẹju kan ati iṣeju aya mejidinlogun lọ.
Awọn to nifẹ fidio naa kọja ẹgbẹrun lọna ọgọrin.
Taa wa ni Lisa Hanna to nb da ori ayelujara ru yi jẹ?
Arabinrin Lisa Hanna jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta ọmọ ilẹ Jamaica.
O jẹ obinrin ilẹ Jamaica kẹta ti wn yoo de lade obinrin to rẹwa julọ lagbaye lọdun 1993.
O ti bi ọmọ kan to si tun jẹ ọmọ gbẹ alatako Peoples National Party ni Jamaica.
Ohun ni aṣoju agbegbe Saint Ann South East nile asofin ilẹ naa.
Ọrọ ko ri bi fọnran fidio to lu ayelujara pa ti se sọ pe o n du ipo aarẹ .
Ni ọdun 2007ni Hanna du ipo to si wọle gẹgẹ bi aṣoju ẹkun idibo rẹ.
Eyi mu jẹ ọkan lara awọn obinrin aṣofin tọjọ ori wọn kere julọ.
Lati 2007, o ti dupo to si wọle lẹẹmẹta ọtọọtọ.Koda o tun fẹ dije ni igba kẹrin.
Yatọ si pe o jẹ aṣofin, o tun di ipo Minisita fọr ọdọ ati aṣa ilẹ naa laarin ọdun 2012 si 2016
Ki lawọn eeyan n sọ loju ayelujara?
Ojuloge ni Lisa'
Lisa jẹ eeyan to gbafẹ to si tun maa n ṣoge daada.
Eyi mu ki awọn eeyan lorileede maa bẹnu atẹ lu wi pe o yẹ ki o fodinwọn si oge siṣe.
Ọrọ yi ka Lisa lara debi wi pe o kọ apilẹkọ kan lati fi da awọn to n tabuku r lohun.
Ti Lisa ba wole sipo aṣofin to n du lọwọ, yoo jẹ igba kẹrin ti o ṣoju awọn eeyan rẹ lati ọdun 2007 to ti bẹrẹ.