Aisha Buhari: Ìyawó ààrẹ padà délé láyọ̀ láti Dubai

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọkọ̀ Bàálù mi rí ìdámú nínú afẹ́fẹ́ ṣùgbọ́n...

Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria ti ṣalaye bo ṣe mori bọ lọwọ ọkọ baalu to ri idamu loju ofurufu lasiko to n rinrinajo pada bọ wale lati ilẹ United Arab Emirates (UAE).

Arabinrin Aisha Buhari ni oun rinrinajo lọ si orilẹede naa lati lọ fun itọju to so pada wale pẹlu ọkọ ofurufu ileeṣẹ ogun ofurufu Naijiria.

"Mo fi asiko yii dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria fun adura ati ọrọ ikini wọn nigba ti mo lọ fun itọju. Ara mi ti ya bayii mo si ti pada bọ sipo bẹẹni mo ti dari wale si Naijiria"

Ko ye iru aisan pato to ba aya aarẹ kuro ni Naijiria ṣugbọn ko ba a pada wale gẹgẹ bo ṣe sọ.

Ẹwẹ, o ni "loju na wa pada, ọkọ baalu awọn ọmọ ogun ofurufu ri idamu nla ninu ofurufu ṣugbọn awakọ atawọn oṣiṣẹ inu baalu naa ṣe iṣẹ takun takun lati da a pada sọna rẹ".

Aisha gboriyin fun igboya ti awakọ naa atawọn oṣiṣẹ toku ni si iṣẹ wọn.

Lootọ, Aisha Buhari lọ Dubai

Iroyin to n ja rayin-rayin lori ayelujara ni wi pe iyawo aarẹ orilẹede Naijiria ti rinrinajo lọ si Dubai ni orilẹede United Arab Emirate fun idi pato ti a ko mọ.

Awọn iroyin kan tilẹ n sọ pe bi awọn ṣe gbọ ọ, ọrun lo n dun arabinrin Aisha ṣugbọn iroyin naa sọ pe awọn apẹrẹ ṣaa han pe tori ilera rẹ ni.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti fọn si oju opo Twitter lati sọ ero wọn nipa irinajo ti a gbọ pe iyawo aarẹ lọ yii.

Igba ti a ri iyawo aarẹ kẹyin ni ita gbangba ni asiko adura ọdun Eid-el-Kabir pẹlu awọn idile rẹ nile Aso Villa nilu Abuja.

Awọn iroyin mii ni lẹyin ọdun Sallah lọsẹ to kọja ni wọn gbe iyawo aarẹ kuro ni Naijiria lẹyin to n kerora ọrun didun lati bi ọsẹ meji to bere fun ki wọn gbe oun lọ oke okun.

Kí ló mú Aisha Buhari figbe bẹnu pé kí Ọ̀gá Ọlọ́pàá tú àwọn ẹ̀sọ́ rẹ̀ sílẹ̀?

Ọrọ miran tun ti n rugbo bọ nidile aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari pẹlu bi iyawo aarẹ Aisha Buhari ti se ke gbajare si ọga ọlọpaa lati tu awọn ẹsọ oun silẹ ki wọn ma ba lugbadi Covid-19 lọdọ wọn.

Aisha fi ọrọ yi sita lọjọ Eti si oju opo Twitter nibi to ti sọ awọn ọrọ pe ko yẹ ki ẹnikankan kọja ofin ti ijọba gbe kalẹ nipa irina lasiko Covid-19 .

Aisha ni ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ si ofin yii gbọdọ lọ si iyasọtọ ọlọjọ mẹrinla lati le mọ boya o ko arun naa tabi ko ni.

O pari ọrọ rẹ pe ki ọga ọlọpaa tu awọn ẹsọ oun ti wọn mu sọdọ silẹ ki wọn ma ba ko Covid-19.

Ta lẹni ti o tapa si ofin bawo lo si sẹ kan awọn ẹsọ Aisha Buhari?

Ninu ọrọ ti Aisha Buhari sọ, ko darukọ ẹni kankan pe o tapa si ofin ma rina lasiko Covid 19.

Sugbọn o jọ gate ko jọ gate, awọn ileesẹ iroyin Naijiria kan sọ pe ọrọ yii ko sẹyin bi ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari kan ti se dari si Aso Rock lati irinajo si ipinlẹ miran ni Naijiria.

Gẹgẹ bi wọn ti se sọ, awọn ẹsọ Aisha Buhari ko jẹ ki amugbalẹgbẹ yi wọ Aso Rock nitori pe wọn ni o seese ki o ti ko Covid-19 lati ibi to ti n bọ.

Amugbalẹgbẹ yii la gbọ pe o fi ibinu pe olori awọn alaabo iyẹn CSO ti o si ni ko fi awọn ẹsọ iyawo aarẹ to da lọna si ahamọ.

O seese ki o jẹ idi ree ti Aisha Buhari fi n lọgun sugbọn a ko ti ridi ọrọ yi fi mulẹ.

Ileesẹ ọlọpaa Naijiria naa ko ti fesi boya lootọ lawọn ẹsọ iyawo aarẹ wọn wa lahamọ.

Awọn ọmọ Naijiria ni imọtaraẹni lo n damu Aisha Buhari

Kete ti Aisha Buhari fi ọrọ yi sita loju opo Twitter lawọn eeyan yabo oju opo rẹ ti wọn si bẹrẹ si ni fesi.

Ọpọ ko tilẹ beere ohun ti o mu ki Aisha Buhari ke gbajare si ọga ọlọpaa.

Ninu ero wọn, Aisha Buhari ko tori awọn eeyan sọrọ nipa titẹle ilana ijọba lasiko Covid-19 yi bi kii se pe eeyan kan tun ti fọwọ tẹ ẹtọ rẹ mọle ni

Awọn kan tilẹ n beere pe se ko ni nọmba ọga ọlọpaa ni abi ki lo wa de to fi n damu awọn loju opo Twitter

Ninu ero awọn ẹlomiran, wọn ni se ko yẹ ki iyawo aarẹ da si awọn ọrọ miran to n jẹ Naijiria logun lasiko yi bi ipaniyan ati ijingbe to n waye lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria.

Buhari yóò báwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lọ́la 'June 12' tí ṣe àyájọ́ ìjọba àwarawa

Aarẹ orillẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo bawọn eeyan sọrọ lọjọ Ẹti, ọjọ kejila oṣu to ti di ayajọ ijọba awarawa bayii.

Gẹgẹ bi atẹjade ti oludamọran pataki si aarẹ, Femi Adesina fi sita, aago meje aarọ ọjọ Ẹti ni Buhari yoo bawọn ọmọ Naijiria sọrọ.

Ijọba rọ awọn ileeṣẹ redio ati amohunmaworan to fi mọ awọn ileeṣẹ iroyin mii pe ki wọn darapọ mọ ileeṣẹ tẹlifisan ijọba apapọ, NTA lati le ṣafihan ọrọ fawọn eeyan.

Ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 1993 lawọn ọmọ Naijiria dibo aarẹ ninu eyi ti MKO Abiola ti ẹgbẹ SDP ti waako pẹlu Alhaji Bashir Tofa ti ẹgbẹ NRC.

Abiola lo jawe olubori ibo naa, ṣugbọn Ọgagun fẹyinti Ibrahim Babangida wọgile esi idibo naa eleyi to da rogbodiyan silẹ kaakiri Naijiria nigba naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lọdun 2018 ni Aarẹ Buhari kede ''June 12'' gẹgẹ ayajọ ọjọ ijọba awarawa dipo ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ti ijọba ologun gbejọba fun alagbada ti ijọba kede tẹlẹ.