Sunday Shodipe: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ṣe àfihàn afurásí tó n pààyàn ní Akinyele

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe afihan Sunday Shodipẹ, afurasi ọdaran ti wọn fi ẹsun kan wi pe o n da ẹmi awọn eeyan legbodo ni ijọba Ibilẹ Akinyẹle.

Ni nnkan bi aago mọkanla owurọ Ọjọru ni kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwachukwu Enwonwu fi oju Sunday ati awọn ọdaran mii ti wọn ri mu han fun gbogbo aye ri ninu ipade awọn oniroyin to waye ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹle nilu Ibadan.

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, afurasi naa sọ pe ni agọ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Mọkọla ni oun ti salọ nigba ti wọn ṣi oun ati awọn ọdaran mii ti wọn jọ wa ni atimọle silẹ lati lọ wẹ.

O fi ẹsun kan oṣiṣẹ ọlọpaa kan to pe ni Funṣọ, pe oun lo fi aye silẹ fun oun lati sa lọ.

Sunday fi kun ọrọ rẹ pe, bẹẹ ni ko si se lẹyin baba ti oun n ba ṣiṣẹ naa bo tilẹ jẹ wi pe baba naa n bẹ ninu gbaga ọlọpaa.

Lẹyin ti o sa lọ lo tun lọ ṣekupa pa arabinrin kan ni agbegbe Akinyẹle, bẹẹ sini o tun da ọgbẹ si ẹlomii lara.

Afurasi naa tẹsiwaju pe ni agbegbe Bodija ni oun ti n ṣiṣẹ alaaru lẹyin to sa kuro ni ahamọ ki o to bọ sọwọ wọn.

Bẹẹ si ni o ni oun maa n da fila bo oju ki ẹnikẹni ma baa da a mọ.

Sunday ni kii ṣe ọlọpaa lo mu oun ni Bodija.

O ni arakunrin kan lo ni ki oun ṣe iranlọwọ lati ba oun ti ọkọ lai mọ pe o fẹ mu oun ni.

Arakunrin naa ati awọn ẹlomii lo faa le ọlọpaa lọwọ.

Ninu ọrọ tirẹ, kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwachukwu Enwonwu ṣe alaye fun awọn oniroyin pe aaye ti ko si ni ọgba ẹwọn lo jẹ ki wọn fi Sunday pa mọ si agọ ọlọpaa kan ni Mọkọla.

O tẹsiwaju pe nibayii ti wọn ti ri i mu pada lẹyin ti o salọ mọ wọn lọwọ, o ti di dandan ki wọn sọ ọ si ọgba ẹwọn nibi ti eto aabo ti fi ẹsẹ mulẹ daadaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ni oṣiṣẹ ọlọpaa ti Sunday fi ẹsun kan wi pe o ṣi awọn silẹ ti n foju wina ibawi.

Awọn ọdaran to fọ ile ifowopamọ First Bank nilu Okeho naa ko gbẹyin ninu awọn ọdaran ti wọn fi oju wọn han, to fi mọ awọn ara ilu kan ti wọn tun ji owo ti wọn ri gba lọwọ awọn ọdaran ọhun.

Sunday Shodipe: Àlàyèé rèé lórí bi wọ́n ṣe ri ọ̀daràn tó n dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn légbodò l'Akínyele

Àwọ́n àṣìrí míràn tún ti jẹyọ lórí bi ọwọ́ ṣe tẹ afunrasí ọ̀daràn Sunday Shodipe tí àwọn ọlọpàá ni àwọn gbé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Naira kalẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tó ba ri i mú.

Lọ́sàn àná ni ìròyìn gbòde pé wọ́n ti ri ọ̀dọ́mọde náà mú tí ó sì ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo Olugbenga Fadeyi ṣe sọ fun ilé iṣẹ́ BBC

Ìbéérè tó tún tèlé e ni pé Báwo ni wọ́n ṣe rii mú gan-an

Ìdí èyí ni ilé iṣẹ BBC fí ṣe ìfòrọ̀wánilẹ́nu wò fún àwọn tó lọ́wọ́ nínú ọ̀nà ti wọ́n fi mú ọmọkùnrin náà.

Ààrẹ ẹgbẹ́ ọdẹ Soludẹrọ nílùú Ibadan Nureeni Ajijolaananbi sàlàye fún BBC Yoruba pé, ní àkọ́kọ́ ti ọlọ́pàá mú Sunday Shodipe náà, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọdẹ Soludẹrọ ni.

Ó ní ní kété ti ó sì tún bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá padà ni iṣẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ lórí bi wọ́n yóò ṣe ri mu, Ó ní àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ni bọ ogún gbígbóna pé gbogbo ibi ti ó bá wa ki èsù tìí síta.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn kan sọ pé, ọdọmọkunrin kan ti orúkọ rẹ̀ jẹ́ Isaac Bamidele lo fí ibúdó rẹ̀ sílẹ̀ ni ìlú Akure tí o si wá fi ilú Ibadan ṣe ibùgbé láti ri ọmọkùnrin náà mú.

Sùgbọ́n, ààrẹ Soludẹrọ̀ sọ pé, lóòtọ́ ni sùgbọ́n àwọn jọ fi ọwọ́ sọwọ́pọ̀ ni ti àwọn fi ri ọmọkùnrin náà mú.

Nínú àlàyé Isaac Bamidele to jẹyọ lórí ayélujára, Isaac ni òun fi ilú Akurẹ silẹ̀ láti wa gba òtẹ́lìì sí agbègbè Mọniya ni ilú Ibadan pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ òun kọọkan tí àlàyé sì ti wà lórí ǹkan ti ó fẹ́ wá ṣe.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ní "Mo sàkíyèsí pé agbègbè Akobọ̀ lo máa n jòkó si to si ti lọ máa n ra igbó, ọ̀rẹ́ mi lo ti maa n ri nibi ojú irin to wa lọ́nà Barack tẹ́lẹ̀ to ti lo ti ma ń ra igbó.

"Nígbà ti a ri mó fẹ́ lọ bá awọn boys mi, agbègbè ibi ti o maa n wà ni, ni a ri pẹlú ọmọ kekere kan, mo wa dúro si bi móto mi ti tayà rẹ̀ fọ́, mó dọ́gbọ́n bi pe mò n gba ìpè, sùgbọ́n àwọn ọ̀rẹ mi ti n tẹ̀le bọ̀.

"Nígbà ti o dé ẹ̀gbẹ́ mi, mo wa bẹ̀ẹ́ ki ó bá mi ti móto mi, o sì bá mi tìí, mo wá ni ki ó jọ̀ọ́ kó bámi tìí díẹ̀ sí pé màá fún ní ǹkan kan."

"Bó ṣe bá mi ti móto yẹn tan, mo wa ni ó jọ bi ẹni pé mọ́tò náà kò ni ṣiṣẹ́ pé o ṣeun àti pé mó fẹ́ lọ pe ẹni ti yoo ba mi tún ṣe."

"Mó wá ni kí n dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó ṣeun tó bá mi ti mótò, bi mọ ṣe mu nìyẹn"

Lórí owó ti àjọ ọlọ́pàá fi léde pé àwọn yóò fún ẹni to bá rí ọ̀dọ́mọkùnrin Sunday Shodipe mú

Ààrẹ ẹgbẹ́ ọdẹ Soludẹrọ Ajijọlaanabi ní àwọn ọlọ́pàá ti n ṣeto bi owó náà yóò ṣe tẹ àwọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bi ìlérí wọ́n.

Lọwọlọwọ, oriṣiriṣi ni awọn ileeṣẹ iroyin ti n gbe nipa rẹ. Bi awọn kan ṣe n fi sita pe sisa to salọ ko ṣẹyin ọga ọlọpaa kan, lawọn mii n ni ile iya iya/baba rẹ ni wọn ti pada ri i mu ṣugbọn a o tii le fidi eleyii mulẹ.

Koda, awọn ikọ alaabo kan niluu naa n sọ pe awọn lawọn ṣokunfaa bi ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ ẹ pada.

Ẹwẹ, ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria Mohammed Adamu ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ orileede Naijiria fun atilẹyin wọn eyi to ja si bi wọn ti ṣe mu Sunday Shodipe.

Arakunrin yii ni afurasi ti o sa mọ ileeṣẹ ọlọpaa ilu Ibadan lọwọ ṣugbọn ti wọn ti ri mu pada ni Bodija lọjọ Aiku.

Ninu atẹjade kan ti Frank Mba fi sita lorukọ ọga agba ọlọpaa, o ni Sunday Shodipe jẹ afurasi ninu ipaniyan to waye nijọba ibilẹ Akinyele.

Mohammed Adamu wa kilọ fawọn agbofinro lati ma ṣe jẹ ki ina esisi tun jo wọn lori ọrọ yi ki wọn si ṣapa lati yanju ẹjọ to wa nilẹ yi.

'Mo lè fọwọ̀ sọ̀yà fún yín pé Sunday Shodipe ti wà láhàmọ́ wa - Alukoro Ọlọ́pàá Oyo

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti tẹ arakunrin kan, Sunday Shodipe to sa mọ wọn lọwọ laipẹ yi.

Shodipe jẹ afurasi ti wọn ti kọkọ mu lori iṣẹlẹ iṣekupaniyan to n waye lẹnu lọọlọ yi lagbegbe Akinyele ni ilu Ibadan.

Ko tii daju ibi ti wọn ti ri i mu ṣugbọn BBC Yoruba ba alukoro ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Fadeyi Olugbenga sọrọ o si fidi ọrọ yii mulẹ.

"Mo le fọwọ sọya fun yin bayi bayi pe afurasi ọdaran to sa lọ, Sunday Shodipe ti wa lahamọ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo".

O ni "ẹ o maa gba iwe atẹjiṣẹ latọdọ mi laipẹ".

Bi ẹ ko ba gbagbe, iroyin jade rẹpẹtẹ nigba ti ọwọ kọkọ tẹ Shodipe to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun koda ati igba to tun sa lọ mọ ọlọpaa lọwọ, iroyin ko tii tan nilẹ titi di akoko yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, o ti pẹ diẹ ti iroyin sọ pe afurasi ọdaran yii lo wa nidii iku ọwọwọ to n waye lagbegbe ijọba ibilẹ Akinyele nipinlẹ Oyo.

A n ṣe akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ.

Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.