Akinyele murder: Àwọn aṣekúpani tún ti pa ọmọ ọdún 16 ní Akinyele nípìnlẹ̀ Oyo

Ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Toke, ti di ero ọrun lẹyin ti awọn kan pa a nijọba ibilẹ Akinyele, nipinlẹ Oyo.

Owurọ Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin sọ pe wọn ri oku Toke ninu igbo kan ni agbegbe Onikoko, loju ọna Ibadan silu Oyo.

A gbọ pe awọn obi Toke lo ran an lọ ọ ra epo bẹtiro ni nkan bi aago mẹsan an alẹ lọjọ Aje, ṣugbọn ko pada sile.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa lati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Moniya ri oku rẹ ninu igbo naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi, sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Iku Toke ni ikẹfa to ti waye nijọba ibilẹ Akinyele laarin oṣu meji. Ọsẹ to kọja si ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe oun ti mu awọn afurasi ọdaran kan to n pa awọn eniyan naa.