You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo APC Primary: Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn akẹgbé mi nínú ẹgbẹ́ sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti sọ pe oun ti bẹrẹ igbesẹ alaafia laarin rẹ atawọn akẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ naa.
Akeredolu lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
O ni "Adupẹ fun aṣeyọri ti a ri ninu idibo abẹlẹ ti a ṣe kọja, ṣugbọn oun to wa niwaju wa ṣi ju iṣẹgun ti a ti ni sẹyin lọ."
Gomina ọhun ṣalaye pe ifọwọsowọpọ nikan lo lee mu itẹsiwaju ba ẹgbẹ oṣelu APC ati ipinlẹ Ondo, nitori naa ni o ṣe gbe igbesẹ ọhun, ki alaafia lee jọba.
Ni bayii, Akeredolu ti lọ ṣabẹwo si awọn ti wọn jọ dije ninu idibo abẹle naa, lara awọn ni Olusola Oke, Salo Iji ati D.I Kekemeke.
- 'Adarí àjọ NDDC, Pondei ń ṣe àìsàn ló ṣe dákú lásìkó ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò'
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
- Kùdìẹ̀kudiẹ wà nínú ìbò abẹ́nú APC tó yan Akeredolu, ṣùgbọ́n...
- Ìjọba Nàìjíríà ti parí ìwádìí lórí àgbo Covid-Organics ti Madagascar kó ránṣẹ́ sí i
Akeredolu lo jawe olubori ninu abẹle to waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati yan oludije sipo gomina ninu idibo ti yoo waye loṣu kẹwaa ọdun 2020.
Ṣaaju idibo abẹle naa ni oriṣiriṣi nnkan ti n ṣelẹ ninu iṣejọba Akeredolu, akọkọ ni pe igabkeji rẹ, Agboola Ajayi fi ẹgbẹ APC silẹ, to si lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ko pẹ si asikọ ọhun ni akọwe ojọba rẹ, Ifedayo Abegunde naa kọ ẹyin si Akeredolu.
Olusola Oke ní ìfẹnukò àwọn alátìlẹ́yìn òun ni yóò sọ ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn ìdìbò abẹ́nú APC l'Ondo
Lootọ lawọn aidọgba pọ nipa eto idibo abẹle APC to waye lana nipinlẹ Ondo, ṣugbọn n o tii le sọ igbesẹ to kan fun mi bayii- Olusola Oke.
Amofin Oluṣọla Oke to jẹ ọkan lara awọn oludije nibi idibo naa lo sọ eyi fun BBC News Yoruba.
O ni oun yoo ṣepade pẹlawọn alatilẹyin ohun lati mọ ibi ti awọn yoo gbe ka.
Amofin Oke ni ṣaaju eto idibo naa loun ti pariwo sita pe o ni kudiẹkudiẹ ninu eleyi ti ẹnikẹni ko fi lee tọka si ọrọ oun gẹgẹ bii ẹni to n ṣawawi nigba ti oun fidirẹmi.
- Dárúkọ àwọn tọ ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ NDDC tàbí kí o fojú winá òfin- Gbajabiamila sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Akpabio
- Isa Funtua, Abba Kyari àti Zulaihat Buhari jẹ́ àwọn tó súnmọ́ Aàrẹ tó papòdà láìpẹ́
- Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ TRACE tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
- Wo àwọn tí Pondei fara jọ pẹ̀lú ààrẹ̀ níwájú ijẹ́jọ́
Ṣé lootọ ni àwọn Agba ẹgbẹ ṣe atilẹyin fún oludije kan?
Lori boya awọn agbaagba ẹgbẹ naa ṣe atilẹyin fun ọkan ninu awọn oludije naa, amofin Oke sọrọ ni kikun.
O ṣalaye wi pe ni ti oun o, ko si ifarahan awọn agbaagba ẹgbẹ kọkan ni ilu Akurẹ lọjọ ti idibo naa waye.
Awọn aṣoju ẹgbẹ ni ipinlẹ Ondo lo dibo yan ẹni to wọle, nitori naa gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tootọ, ko si idi fun oun lati sọ pe bẹẹni tabi bẹẹkọ lọwọ yii.
Gomina Akeredolu ni wọn kede gẹgẹ bii olubori ibo abẹnu lati mọ ẹni ti yii gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni idibo gomina ipinlẹ Ondo to n bọ lọna ti amofin Oluṣọla Oke si gbe ipo keji.
Lẹ́yìn gbogbo sinimá oríta ní Ondo, Akẹti jáwé olúborí ní APC
Èsi idibo lati yan ẹni ti yoo dije du ipo gomina fun ipinlẹ Ondo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti jade. Aketi lo gebgba oroke ju.
Lẹyin gbogbo sinima orita awoo wo tan to ti ṣẹlẹ sẹyin ni ipinlẹ Ondo, Gomina Rotimi Akeredolu to ti tukọ ipinlẹ naa lọdun mẹrin sẹyin ni o tun ri tikẹẹti gba lẹẹkan sii Mo káàbámọ̀ pé mo yan Ajayi gẹ́gẹ́ bíi igbákejì mi- Akeredolu .
Bayii ni esi idibo naa ṣe lọ:
Ibrahim Olusegun Michael PHD........ 0Adelami Olayide Owolabi MNI.......4Adetula olubukola Olarogba Okunola.....0Adejutelegan Nathaniel Olumuyiwa DR......4Akeredolu Oluwarotimi Odunayo SAN..........2458Anifowoshe Olajumoke Olubusola......2Awodeyi Akinsheyinwa Akinola Colinus......1Iji Olusola Joseph...... 9Kekemeke Duerimini Issac.....19Odimayo Okunjimi John......0Oke Olusola Alex SAN......262Oyedele Ifeoluwa Olusola.....1
Bawo ni Idibo APC Ondo ṣe lọ?
Ètò ìdìbò abẹ́lé sípò gómìnà APC ni ipinlẹ Ondo ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu
Eto idibo abẹle lati mọ ẹni ti yoo gbe apoti ibo sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ondo bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Bi wọn ṣe n yẹ kaadi idibo awọn olukopa ninu idibo abẹle ọhun wo naa ni wọn n dibo lẹsẹkẹsẹ.
O kere tan, ẹgbẹrun mẹta awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati ẹkun idibo mẹtalenigba kaakiri ipinlẹ Ondo lop n kopa ninu idibo abẹle naa lati yan ẹni ti yoo gbe apoti ibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.
Ṣaaju ni mẹta lara awọn to n ba gomina Rotimi Akeredolu dije ti kọkọ sọ pe wọn ko ṣe mọ.
Awọn eeyan naa ni Segun Abraham, Ife Oyedele ati Jimi Odimayo.
Ẹwẹ, iroyin ti kọkọ gbode pe ọkan lara awọn oludije ọhun, Nathaniel Adojutelegan ti yọwọ lawo lati dije ninu idibo abẹle naa, ṣugbọn o sọ fun BBC pe irọ pọmbele ni.
Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?
Àwọn olùdíje meji míràn tún ti jọ̀wọ́ àgá fún Akeredolu níbi ètò ìdìbò abẹ́lé APC ìpínlẹ̀ Ondo
Ni kete to ku wakati diẹ ki eto idibo abẹle lati mọ ẹni ti yoo gbe apoti ibo sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ondo bẹrẹ, oludije meji miran tun ti yọnda aga fun gomina Rotimi Akeredolu.
Akeredolu lo fi ọrọ naa ledeloju opo Twitter rẹ lẹyin ti ileeṣẹ iroyin abẹlẹ kan kede rẹ.
Awọn oludije ọhun ni Ife Oyedele, Jimi Odimayo.
Ṣaaju ni Akeredolu ti kede loju opo Twitter rẹ kan naa pe ọkan gboogi lara awọn to n ba du ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣẹlu naa, Olusegun Abraham ti yọwọ rẹ kuro lawo idibo ọhun.
Igbesẹ tuntun yii ti mu ki iye awọn to n ba gomina Akeredolu figa-gbaga ninu idibo abẹle naa, ṣugbọn ti wọn jawọ di mẹrin.
O le lẹgbẹrun mẹta awọn ọmọ oṣelu APC lati ẹkun idibo mẹtalenigba kaakiri ipinlẹ Ondo ti yoo kopa ninu idibo naa lati yan ẹni ti yoo gbe apoti ibo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.
Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 ni idibo sipo gomina ọhun yoo waye.
Ondo APC primaries: Olùdíje míràn, Olusegun Abraham tún ti gbé àgá fún Akeredolu níbi ètò ìdìbò abẹ́lé APC ìpínlẹ̀ Ondo
Bi awọn aṣoju oludibo lẹgbẹ oṣelu APC ṣe n gbaradi lati yan oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun ibo gomina to n bọ lọna, oludije miran tun ti dide lori aga fun gomina Rotimi Akeredolu.
Gomina Akeredolu ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe Oluṣẹgun Abraham to jẹ okan lara awọn oludije mẹwaa to n ba a ta kangọn ti gba lati ti oun lẹyin.
"Mo ṣẹṣẹ ba ọmọ iya mi, Oluṣẹgun Abraham sọrọ tan lori foonu ni, o si ti jẹ ko di mimọ fun mi peoun ṣetan lati fọwọ si idije mi nigba keji. Ni ifọwọsowọpọ la o js mu ki oorun ipinlẹ Ondo o tubọ maa tan sii."
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, eto ti n lọ ni pẹrẹ lawọn ibudo idibo abẹle lẹgbẹ oṣelu APC ni ilu Akurẹ.
Akọroyin BBC News Yoruba to wa nibi idibo naa ṣalaye pe awọn aṣoju ọmọẹgbẹ gbogbo to fẹ dibo ni wọn ti wa nikalẹ ti wọn si n reti ki eto naa bẹrẹ.
Ni Gbongan The Dome, awọn apoti idibo gbogbo ti wa ni ato ni isọri ijọba ibilẹ kọọkan.
Bakan naa lawọn agbofinro naa wa ni sẹpẹsẹpẹ lati rii pe ẹkọ ṣoju mimu lori abo ẹmi ati dukia nibẹ.
Wo bí ètò ìdìbò abẹ́lé APC yóò ṣe lọ ní ìpínlẹ̀ Ondo lónìí
Loni ni ireti wa pe awọn aṣoju oludibo lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo yoo gbe ipinnu wọn kalẹ lori ẹni gan an ti wọn fẹ ko gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa ninu eto idibo sipo gomina to n bọ lọna.
Kii ṣe ahesọ ọrọ mọ pe oniruuru awuyewuye lo ti wọ tọ ọrọ tani yoo dije ipo gomina ni ipinlẹ Ondo.
Awọn oludije mọkanla lo n dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC naa bayii lẹyin ti iroyin abẹle sọ pe Ifẹ Oyedele, ọkan lara awọn oludije naa to fi pe mejila tẹlẹ ti gba lati jawọ.
Ifẹ Oyedele ni oun gbe igbesẹ naa lati lee ṣe atilẹyin fun gomina Rotimi Akeredolu.
Oyedele kede atilẹyin rẹ fun Akeredolu lẹyin ifikunlukun pẹlu gomina Akeredolu nileejọba ipinlẹ Ondo ni alẹ ọjọ Aiku.
Gomina Yahaya Bello ni alaga igbimọ to n ṣe kokari idibo abẹle naa; oun pẹlu si ṣepade pẹlu gbogbo wọn lalẹ ọjọ Aiku kan naa.
Awọn ibudo ayẹwo fawọn aṣoju oludibo niwọnyii:
Awọn aṣoju lati ẹkun Ariwa Ondo- Gbongan ajọ olomi ẹrọ Water Corporation to wa ni Ijapo Estate,
Awọn aṣoju ẹkun Gusu Ondo- Ileewe girama, St Thomas' Aquinas College nilu Akurẹ
Awọn aṣoju ẹkun Aringbungbun Ondo- Ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, ODHA Complex ni opopona Igbatoro Akurẹ.
Awọn oludije pe fun isunsiwaju idibo abẹle naa
Nibayii, iroyin n sọ pe meje ninu awọn oludije naa ni wọn ti n pe fun isunsiwaju idibo abẹnu naa.
Amọṣa gomina Yahaya Bello ti ṣalaye pe oun gẹgẹ bi alaga igbimọ ibo abẹle naa ko laṣẹ lati sun un siwaju.
Yahaya Bello ni: "A o tẹsiwaju pẹlu idibo abẹle yii.
Ko si eto idibo to pe nibiki lagbaye, koda titi de orilẹ-ede Amẹrika pẹlu."
Awọn oludije to n dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lati dupo gomina ipinlẹ Ondo ni Gomina Rotimi Akeredolu, Chief Olusola Oke, Dokita Segun Abraham, Ọgbẹni Olaide Adelami,
Ko yọ Bukola Adetula, Arabinrin Jumoke Anifowose, Ambasadọ Sola Iji, Ọgbẹni Isaac Kekemeke, Jimi Odimayo, Ọgbẹni Nathaniel Adojutelegan ati Awodeyi Akinsehinwa naa silẹ.