Kanye West Breakdown: Ìpolongo ìdíje sípò aàrẹ Kanye ti gbéraṣo ní Charleston

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajugbaja olorin ni ilẹ Amerika, Kanye West ti bẹrẹ ipolongo rẹ ni Charleston, ni South Carolina saaju idibo sipo aarẹ lorilẹ-ede naa.

West to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogoji ti bẹrẹ ipolongo rẹ, eyii ti o pe ni "Birthday Party."

Ni ibi ipolongo naa ni West ti sọ ero rẹ lori bi o ṣe tako oyun ṣiṣẹ, bi o ti lẹ jẹpẹ awọn eniyan ko gba ipolongo rẹ gbọ.

West ni oun faramọ ki awọn eniyan ni eto labẹ ofin lati ṣẹ oyun, amọ ki ijọba ṣe ipese owo fun awọn oloyun ti ko ba ri owo lati tọju ara wọn.

Awọn ololufẹ rẹ ni o ṣeeṣe, ki o fi lede pe oun fẹ dije dupo nitori a ti ta awọn orin tuntun ti o fẹ gbe jade.

Bakan naa ni ipolongo idibo naa ti o ṣe ni Charleston ko fi idi rẹ mulẹ boya lootọ ni o fẹ fi gbogbo ara dije dupo naa tabi ofege ni.

Kanye West : Ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Kanye West rèé

Ariwo Kanye West gba ori ayelujara kan lọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2020 lẹyin to fi ikede sita pe oun fẹ du ipo aarẹ ilẹ Amẹrika.

Ikede naa jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ rẹ ti yoo sọ pe oun fẹ di aarẹ ni eyii.

Wo awọn ohun marun un to yẹ ki o mọ nipa gbajugbaja olorin takasufe naa:

Kanye West ti fẹ Alexis Phifer ri:

Ko to di pe West gbe Kim Kardashian niyawo, o ti figba kan kọ ẹnu ifẹ si Alexis Phifer, to si sọ pe oun yoo gbe niyawo.

Wọn ti bẹrẹ ere ifẹ wọn lati ọdun 2002 ti wọn si n mura igbeyawo, ṣugbọn ere ifẹ ọhun fori sogi.

Biliọnia ni kanye West

O ti to nnkan bi ọdun diẹ sẹyin ti West ti darapọ mọ awọn abulẹṣowo biliọnia nilẹ Amẹrika.

O tilẹ ti fi igba kan bu ẹnu atẹ lu ajọ to n gboriyin fun awọn eeyan nitori aṣẹyọri wọn, Forbes pe wọn kọ lati fi orukọ oun si ara awọn biliọnia nitori pe oun jẹ alawọ dudu.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Forbes fi lede, idiyẹle Kanye West ko din ni biliọnu kan ati ọọdunrun miliọnu dọla, ṣugbọn West yari pe oun niye lori ju bẹ lọ.

Kanye West lo ni ileeṣẹ Yeezy to n ṣe bata

Lati ọdun 2013 ni West ti gbe ileeṣẹ to n ṣe bata tirẹ jade, iyẹn Yeezy, pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ Adidas.

Ileeṣẹ Yeezy ti gbe awọn itẹlẹ kan jade, eyi tawọn eeyan kan sara si pe o dara pupọ.

Ṣugbọn olorin naa ti yi orukọ ileeṣẹ ọhun kuro Yeezy si Ye.

Ọmọ meje lo wu Kanye West lati bi

Lọwọ yii, West ti bi ọmọ mẹrin, ṣugbọn o sọ ninu ifọrọwerọ kan lọdun 2019 pe ọmọ meje pere lo wu oun lati bi.

Ko pẹ si akoko yii ti iyawo rẹ, Kim ardashian fidi ọrọ naa mulẹ pe ootọ ni o wu Kanye West lati bi ọmọ meje.

Psalm ni orukọ ti wọn sọ ọmọ wọn kẹrin.

O ṣe diẹ ti ọkan Kanye West ti wa nipo aarẹ ilẹ Amẹrika

Ṣaaju ni West ti sọ lọdun 2015 pe o wu oun lati du ipo aarẹ ilẹ Amẹrika.

Iwadii si fi han pe oludije kan ti orukọ rẹ n jẹ "Kanye Deez Nutz West" fi orukọ silẹ lati dije labẹ asia ẹgbẹ oṣẹlu "Green Party" lọdun 2015.

Bẹẹ na lo tun sọ lọdun 2019 pe oun yoo du ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2020, ṣugbọn o pa ọrọ da pe o di ọdun 2024 ki oun to dije.

Bo tilẹ jẹ pe o ti n bọ sori fun Knaye West lati dije sipo aarẹ lọdun gẹgẹ bi ofin awọn ipinlẹ kan ṣe gbe kalẹ l'Amẹrika, awọn onwoye ohun to n lọ kan ti sọ pe biba lo ba, ko tii bajẹ.

Kanye West fẹ́ ẹ̀ díje fún ìdìbò ààrẹ ilẹ̀ America fún ọdún 2020

Gbajugbaja akọrin takasufe nilẹ Amẹrika, Kanye West ti kede pe oun naa yoo du ipo aarẹ ilẹ Amẹrika ninu eto idibo ti yoo waye lọdun 2020.

West to fi ikede naa sita loju opo ayelujara Twitter rẹ lalẹ ọjọ Abamẹta tun sọ pe "Asiko ti to fun wa lati ranti ileri ilẹ Amẹrika, nipa gbigbẹkẹle Ọlọrun, ka si sowọpọ fun ìran ati kikọ ọjọ ọla wa".

Sugbọn ko ti i f'ojuhan boya West ti forukọ silẹ lati gbegba ibo, tabi boya o kan n fi ọrọ naa ṣawada ni.

Ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla, ọdun 2020 ni eto idibo aarẹ ilẹ Amẹrika yẹ ko waye.

Oriṣiriṣi eniyan lo si ti n sọ eero ọkan wọn lori ikede ti West fi sita.

Awọn eeyan kan bi i gbajugbaja onimọ ẹrọ, Elon Musk, ṣe gba pe igbesẹ to dara ni, ti wọn si jẹjẹ atilẹyin fun.

Ṣugbọn awọn miran gbagbọ pe aṣiṣe nla ni yoo jẹ ẹ lati dibo fun Kanye West.

Awọn miran tiẹ gbagbọ pe ipolongo bi West n fi ọgbọn ṣe fun awo orin rẹ tuntun, nitori pe o pẹ ẹ darapọ mọ idije fun idibo naa.