Kanye West: Akọrin tàka-súfè sọ ara rẹ̀ lórúkọ tuntun 'Ye'

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajú-gbajà akọrin tàka-súfé, Kanye West tí ṣe isọmọlorukọ tuntun si 'Ye'.

Nínú ìkéde kan tó fi ṣe ìkójáde orúkọ tuntun nàá lórí Twitter lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, West sọ pé ''orúkọ tí àwọn ènìyàn mọ òun sí tẹ́lẹ̀, Kanye West, ti di orúkọ àtijọ́ báyìí. Mo sì ti pa orúkọ dà sí 'Ye.''

West, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì, ni àwọn kan ti n pè ní orúkọ ìnagijẹ 'Ye' láti bí ọjọ́ mélòó kan, tó sì lò ó fún àkọlé àwo orin rẹ̀ kẹjọ tó gbé jáde nínú oṣù Kẹfà, 2018.

Yàtọ̀ sí pé orúkọ tuntun nàá jẹ́ àgékúrú òrúkọ tí West n jẹ́ nídìí iṣẹ́, West ti sọ níbẹ̀rẹ̀ ọdún pé orúkọ nàá jẹ́ pàtàkì fún òun lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.

Ó ní ''mo gbàgbọ́ pé 'Ye' jẹ́ ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ jùlọ nínú Bíbélì, tó sì túmọ̀ sí ' ìwọ' nínú Bíbélì.

''Mo yí orúkọ mi àtijọ́ Kanye, tó túmọ̀ sí Ọ̀kan ṣoṣo, sí Ye - tó jẹ́ ọ̀nà láti ṣe àtúpalẹ̀ ìrú ènìyàn tí a jẹ́. Àwò orin nàá jẹ́ àròjínlẹ̀ lórí ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn.''

West jẹ́ ọ̀kan lára gbajú-gbajà akọrin tàka-súfèé tó yí orúkọ wọn padà.

Sean Combs tí jẹ́ orúkọ bi i Puff Daddy, P. Diddy tàbí Diddy, ṣùgbọ́n tó tún kéde l'ọ́dún yìí pé 'Love and Brother Love' l'òún tún nífẹ̀ẹ́ sí báyìí.