You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC OSUN DEBATE: Àwọn olùdíje sípò gomina sọ̀rọ̀ lórí ètò Èkọ́
Awọn oludije si ipo gomina ni ipinlẹ Ọsun fi erongba wọn han lori ọna abayọ siṣoro eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọsun.
Awọn oludije lati ẹgbẹ oselu APC, ADP, ADC ati SDP fi ero wọn han lasiko ipade itagbangba ti Ile-Ise Iroyin BBC News Yoruba gbe kalẹ saaju ọjọ idibo si ipo goimna ti yoo waye ni Ọjọ Kejilelogun, Osu yii.
Eto ipade itagbangba naa waye ni gbongan Olagunsoye Oyinlọla ni fasiti ipinlẹ Ọṣun lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan an.
Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, Alhaji Gboyega Oyetola lasiko to n fesi si ibeere nipa eto ẹko to da ẹnu kọlẹ ni ipinlẹ Osun, ni wi pe ijọba to wa ni ipo lọwọlọwọ n gbiyanju lati mu ibugbooro ba eto ẹkọ ati pe o ti dara si i ju ti atẹyinwa lọ. O ni ijọba ṣẹṣẹ san owo fun ile iwe giga Ladoke Akintola University ni Ogbomosọ laipẹ ni.
Ninu ọrọ ti rẹ, oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu ADC, Fatai Akinbade ni awọn yoo da ogo ipinlẹ Osun pada nipa mimu eto ẹkọ lọkunkundun. O mẹnuba ohun tó ni lọkan lati ṣe fun itẹsiwaju LAUTECH ki eto ẹkọ le dara sii ni Ọṣun.
Akinbade ni Ile-iwe giga fasiti LAUTECH ti awọn olukọ ko ki n ye da isẹ silẹ nitori ijọba kò san owo oṣu wọn, sọ pe òun yoo rii daju pe wọn da eto ẹkọ pada si ipo to yẹ ki o wa.
Bakan naa, Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP, Moshood Adeoti ninu ọrọ tirẹ fikun wi pe eto ẹkọ se pataki o ṣe koko si ìjọba òun, ati pe ọna abayọ si isoro eto ẹkọ ni ipinlẹ Osun ni gbigba awọn olukọ to dangajia lati bu iyi kun eto ẹkọ lọna to yẹ. O ni ọrọ LAUTECH yoo jẹ afẹnuko ijọba ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun ni.
Ti a ko ba gbagbe, ni esi idanwo asekagba ile iwe girama WAEC ti wọn fi lede laipe yii, ipinlẹ Osun lo se ipo kọkandinlọgbọn ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji.
Awọn ohun miran ti awọn oludije naa sọrọ le lori ni itẹsiwaju ijọba, iyẹn Kọntínúítì, gbèsè ti ijoba ipinle osun jẹ ile ifowopamọsi banki agbaye, eto ẹkọ fásitì LAUTECH to dẹnu kole, eto ilera alabọde àti àwọn ìbéèrè mìíràn lo jẹyọ ní ìpàdé ìtagbangba Ọṣun.
Olúdíje ẹgbẹ òṣèlú PDP nikan ni kò yọjú síbi ìpàde ìta gbángba ninu gbogbo awọn oludije ti wọn kọwe pe.