You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
RCCG: Adeboye ní ó sàn láti sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó f'àlúfà ju òbí lọ
O ṣe pataki fun awọn ọdọ to ba ṣetan lati ṣe igbeyawo lati kansi alufa ijọ wọn saaju obi wọn.
Alufa Foluke Adeboye to jẹ aya alakoso ijọ Redeem lo gba awọn ọdọ l'Ọjọbọ pe, oniwaasu ijọ wọn lọ yẹ ki wọn kọkọ ri fun imọran nigbati wọn ba n mura lati gbeyawo ki wọn to sọ fun obi wọn.
Alufa Adeboye ti ọpọ eeyan tun mọ si Mummy G.O. tun gba awọn nimọran loju opo Twitter rẹ pe ki wọn ma ṣe fẹ iyawo lawin.
Ki oníkálùkù lọ gba káàdì ìdìbò rẹ ni gẹ́gẹ́ bii agbára láti yan ẹni tó wùú sípò.
Olori gbogboogbo fun Ijọ Redeem Christian Church of God (RCCG) ni agbaye, Enoch Adeboye ti sọ wi pe ko si ohun to kan òun ninu didasi isejọba abẹlẹ ẹgbẹ oselu APC.
Baba Adeboye fi eyi lede lori ẹrọ ikansiraẹni Facebook rẹ̀, lẹyin ti Iwe Iroyin kan sọ wi pe Alaga ẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu sọ fun Baba Adeboye wi pe ko si ohun ti oun le sẹ si saa ẹlẹẹkeji Gomina Akinwunmi Ambode ti ilu Eko.
Ninu atẹjade naa, Baba Adeboye bu ẹnu atẹ lu iroyin wi pe, ko si itakurọsọ kankan to waye laarin Tinubu ati oun.
Adari Ijo RCCG naa wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati gba kaadi idibo wọn ki wọn le se ojuse wọn ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Osu Keji, ọdun to n bọ.
Ti a ko ba gbagbe, iroyin kan wi pe Olori Ijo Redeem, Enoch Adeboye ba alaga ẹgbẹ oselu APC, Ahmed Tinubu sọrọ lori saa keji fun Gomina Ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode.
Bakan naa ni ọpọlọpọ awuyewuye wa lori eni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu APC fun idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Eko.