You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ebenezer Obey: Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
Ilumọọka olorin Juju nni, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi ti salaye lẹkunrẹrẹ nipa bo ti se rin irinajo aye rẹ lagbo orin juju.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, agba ọjẹ olorin Juju naa ni, ifarajin ati ọpọ suuru loun ṣe, ki o to di pe oun wa di ologo laarin awọn olorin Juju.
Ebenezer Obey ni lọjọ ti oun yoo kọkọ yọju si ileeṣẹ rẹkọdi Decca, pe ko gbe awo orin oun jade, oun rin lati adugbo Mushin de Akọka nilu Eko ni, nibi ti ileeṣẹ rẹkọọdi naa wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
''Nigba ti maa fi de ileeṣẹ rẹkọọdi Decca, wọn ko fẹ ki n ri ọga ileeṣẹ naa, ṣugbọn mi o sọ ireti nu, ti mo si sọ fun wọn pe, irawọ ọjọ ọla ni mi.''
Gẹgẹ bi Ebenezer Obey ti ṣalaye, lẹyin ọpọ ẹbẹ ni ọkunrin oyinbo to ni ileeṣẹ rẹkọọdi naa pada gba oun laaye, lati wa kọrin.
Abalọ ababọ, Ebenezer Obey pada gbe awo rẹkọọdi rẹ akọkọ jade labẹ ileeṣẹ naa, ti ọpọ rẹkọdi si pada tẹle.
Ebenezer Obey ni pẹlu aṣẹ Ọlọrun 'mo pada wa di ẹni to ra ileeṣẹ rẹkọọdi ọhun, ti mo si yi orukọ rẹ pada si ‘Afrodisiac records.'
Imọran fawọn ọdọ ode oni:
Nigba to n gba awọn ọdọ nimọran, Obey ni ''Ohun to ba jẹ ẹbun rẹ, ma pa a mọra, tori to ba pa ẹbun rẹ mọra, ko da.''
Chief Commander sọ pe, ilu gangan ni Ọlọrun ran oun wa si aye lati wa kọ, lati kekere si ni oun ti yan ilu naa laayo.
''Ifarabalẹ ati fifi tọkan-tọkan ṣe isẹ pẹlu ifarajin lo ran wa lọwọ lasiko tiwa, gbogbo ohun ti eeyan ba fẹ ṣe, ki o ri wi pe ohun sun mọ Ọlọrun''
Nipa iroyin iku Obey rẹ:
Ebenezer Obey ni eyi kii ṣe igba akọkọ ti awọn eeyan yoo ma sọ ahesọ ọrọ nipa oun.
''Bi wọn ko ba ni mo lu lukudi, wọn a ni mo ṣẹso, tabi ki wọn tiẹ sọ pe mo fi igbo pamọ sinu irinsẹ mi.
Wọn ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, sugbọn eleyi ti wọn ni mo ku yi ṣe mi ni kayeefi pupọ''
Ebenezer Obey ṣalaye pe, n ṣe ni awọn eeyan n pe oun lori aago ilewọ kaakiri agbaye, ti ''ẹlomiran si n bu sẹkun lori foonu nigba ti wọn gbọ ohun mi''
''Iṣẹ ti mo wa ṣe laye ṣi ku, bi mi o si pari rẹ, mi o ni kuro lori eepẹ, orin ṣi ku ti mo ma kọ, ko tii tan''
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
- Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti tẹ àwọn aṣekúpani tó ń ṣọṣẹ́ ní Akinyele
- Ìpínlẹ̀ Eko kéde ọ̀nà àbáyọ sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ lásìkò àtúnṣe afárá Third Mainland
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Ilé aṣofin Ondo fọwọ́ òsì júwe ilé fún aṣòfin mẹ́ta pé wọ́n tàpá sí òfin ilé
Irọ́ ni o, Ebenezer Obey ò kú!
Aṣoju ẹgbẹ orin baba Ebenezer Obey, Tunji Odunbaku ti sọ fun BBC Yoruba pe irọ ni iroyin ti awọn kan n gbe kiri pe gbajugbaja olorin naa ti dagbere faye.
Ṣaaju ni iroyin kan gbode lori ayelujara pe agbaọjẹ olorin juju ọhun ti gbẹmi nile iwosan kan ni ilu London.
Ṣugbọn Odunbaku sọ fun BBC pe ko si otitọ ninu iroyin naa.
O ni "Nnkan bii iṣẹju marun un ṣeyin ni mo ṣẹṣẹ baba sọrọ lori awuyewuye pe wọn papopda, ṣugbọn ko si nnkan kan to ṣe baba, alaafia ni wọn wa."
O tẹsiwaju pe irọ ni pe Ebenezer Obey wa ni ilu oyinbo.
Odunbaku pari ọrọ rẹ pe ilu Eko ni baba wa lasiko ti oun n ba BBC sọrọ, ati pe kokoko lara rẹ le.