You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigerian schools resumption: ASUU ní kí ìjọba má tíì ṣí àwọn ilé ìwé nítorí Coronavirus
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU ti ke si ijọba apapọ lati gbe agadagodo sẹnu ọna awọn fasiti kaakiri Naijiria titi di ọdun 2021 lọna ati dena itankalẹ arun Covid-19.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ijọba apapọ pinnu pe awọn ile iwe Unity Schools ko ni kopa ninu idanwo aṣekagba WAEC to yẹ ko bẹrẹ lọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun yii.
ASUU ni digbi loun wa lẹyin ipinnu ijọba apapọ lati sun idanwo WAEC ọhun siwaju.
Ṣaaju ni minisita eto ẹkọ, Chuwuemeka Nwajiuba ti sọ pe ijọba ti ṣepade pẹlu ajọ WAEC.
Ati pe ajọ naa ti gba lati ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju orilẹ-ede mẹrin miran ni Afrika ti wọn ti n ṣe idanwo WAEC lati mu ọjọ mii fun idanwo ọhun.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeeṣẹ iroyin abele kan, aarẹ ASUU, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ni o yẹ ki Naijiria kọgbọn lara ilẹ Kenya to tilẹkun awọn ile iwe rẹ titi di ọdun 2021 nitori ilera ara ilu lo jẹ ẹ logun.
Ogunyemi ni oun ko fẹ fi ẹmi awọn akẹkọọ wewu lo jẹ ki oun gba ijọba nimọran pe ki ile iwe wa ni titi pa lasiko yii.
O ni ki Obi ati alagbatọ ma fooya lori eto igbaniwọle sile iwe giga awọn akẹkọọ nitori pe ti asiko ba to, ohun gbogbo a yanju bi o ti yẹ.
Ninu atẹjade kan ti ASUU fi lede, o ni ọpọ ile iwe to jẹ ti ijọba ni awọn akẹkọọ rẹ pọ ju kilaasi lọ.
Ati pe ọpọ ko ni omi to dara, eyi ti yoo mu ko ṣoro fun awọn akẹkọọ naa lati tẹlẹ ilana ijinasiraẹni ati imọtoto ara ẹni.
Aarẹ ASUU ni didun lọsan o so lasiko igabniwọle awọn akẹkọọ ti ohun gbogbo to n run ba tan nilẹ ti awọn ọmọ si wa ni alaafia.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ayelujara lori ọrọ ti ASUU sọ ọhun.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe odaa bẹ, lawọn miran n sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ nitrori akoko awọn akẹkọọ n lọ lai duro.