Ogun TRACE: Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun

Kayeefi ni ọrọ da ninu ọgba ileeṣẹ ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, TRACE, lasiko ti ọkunrin kan gbẹmi mi sibẹ.

Iroyin sọ pe ọkunrin naa, Fatai Salami, mu oogun apakokoro nitori pe awọn oṣiṣẹ ajọ TRACE, gba ọkọ rẹ.

A gbọ pe ọwọ awakọ Salami, ni wọn ti gba ọkọ akẹru naa nitori pe o ru ofin to rọ mọ jijade lasiko arun Covid-19.

Ọkọ Salami ti lo ọjọ marun-un ninu ọgba TRACE, nitori pe wọn ni ko san ẹgbẹrun lọna okoolerugba o din marun-un Naira, gẹgẹ bi owo itanran.

Iroyin sọ pe Salami tẹle awakọ rẹ lọ sibẹ lati yanju ọrọ ṣugbọn airi ọkọ naa gba lo mu ki Salami da oogun apakokoro mu.

Ṣugbọn ṣa, awọn alaṣẹ ajọ TRACE, sọ pe awọn ko gba ọkọ lọwọ ọkunrin naa.

Awọn iroyin kan ti ẹ tun sọ pe oludari ileeṣẹ eto irinna kan ni ọkunrin naa, to si jẹ pe ọga rẹ sọ pe iṣẹ yoo bọ lọwọ rẹ ti ko ba ri ọkọ naa gba pada.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyem, ṣe sọ fun BBC, awọn alaṣẹ TRACE sọ pe awọn deede ri ọkunrin naa to joko sinu ọgba ajọ naa ni.

Ati pe nigba ti wọn si gbiyanju lati sọ fun un pe ko kuro ni ayika naa lo yọ nkankan jade ni apo, to si da a mu.

Wọn gbe e digba-digba lọ sileewosan, ko to o gbẹmi mi nibẹ.

Oyeyemi sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ otitọ ọrọ naa, ati lati mọ awọn ẹbi ọkunrin naa.

Gbogbo igbiyanju BBC lati ba awọn alaṣẹ ajọ TRACE sọrọ lo jasi pabo, nitori pe agbẹnusọ ajọ naa, Babatunde Akinbiyi, ko gbe ipe sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ.