You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Violence against women: Oniya ṣá ìyàwó rẹ̀ ládá yánnayànna nítorí ìbálòpọ̀ ló bá ń pariwo pé iṣẹ́ èṣù ni
Ariwo eemọ re, ẹ maa woo niran lawọn eeyan lawọn aladugbo n pa ni ilu Ibulẹ nitosi Akurẹ nigba ti bilisi bẹ silẹ laarin lọkọ laya kan ti ọkọ si tipasẹ bẹẹ yọ ada si iyawo rẹ to ṣa yannayanna.
Abilekọ ni arabinrin Monisola Adeọla ti oun ati ọkọ rẹ si n gbe pọ ki wahala to bẹ silẹ lọjọ buruku , eṣu gbomimu naa, ṣugbọn nigba ti iji wahala naa yoo fi rọlẹ, oju ọgbẹ ada lo kun ara arabinrin naa lati ọwọ ọkọ rẹ pẹlu bi ọkọ rẹ ṣe ṣaa lada yannayanna
Monisola ni òun àti ọkọ rẹ tí jọ ń gbé pọ fún bíi ọdún mẹ́tàdínlógún ṣáájú àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀.
Nígbà tí ó un ṣàlàyé fún BBC Yoruba, arabinrin Monisọla ní àwọn nkan ti o to nkan lo máà ń ná òun lé lórí bíi owó ilé ìwé àwọn ọmọ.
O fi kun un ninu àlàyé rẹ pé, nígbà tí òun kò gbà fún ún láti ni ajosepo pelu òun, ìbínú náà lo mú ṣá gbogbo ara òun báyìí.
Ọgbẹni Oniya Adeola tí ó jẹ ọkọ ọmọ obìnrin náà ṣàlàyé pé kò ye òun bi ọrọ naa ṣe jẹ ati pe bi eedi lọrọ ọhun fẹ jọ loju oun.
O ni òun kò mọ ìgbà tí ada de ọwọ òun ti oun si fi ṣá ìyàwó òun.
Oni ìṣe èṣù ni ati pe inú burúkú lo bí òun
Oniya, ẹni tí ó jẹ ọlọkada láàárín ìlú náà sì ìlú Àkúré, ní o ti tọrọ aforiji lọ́wọ́ ìyàwó rè pé ìṣe èṣù ni.