Kumuyi Bible: Ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni òun àtàwọn onímọ̀ Yorùbá fi ṣe ìwádìí nípa Bíbélì náà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laipẹ yii ni Alufa Agba fun ìjọ Deeper Christian Life Ministry, W. F Kumuyi, gbe Bibeli Yoruba to ṣe jáde.

Bibeli tuntun yii si ni ko tii rinlẹ laarin awọn onigbagbọ, to si tun kun ara awọn Bibeli miran to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Ninu ọrọ kan to sọ, Bibeli naa to pe ni Bibeli Mimo Atoka, Kumuyi sọ pe, oun sisẹ pọ pẹlu awọn onimọ èdè Yoruba fun ọdun mẹẹdogun, fun iwadii to yẹ, ki kikọ ati títẹ̀ rẹ to o pari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ki ni awọn nnkan to wa ninu Bibeli naa?

Gẹgẹ bi Alufa Kumuyi ṣe sọ, awọn amuyẹ yii ni Bibeli Mimọ Atọka naa ni:

  • Ọdun mẹẹdogun lo gba ki wọn o to o tẹ sita
  • Kii ṣe pe Alufa Kumuyi kọ bibeli miran, amọ, o sọ pe oun ṣe ogbufọ ede oyinbo ni, sugbọn ni ede Yoruba to rọrùn lati kà fún ẹnikẹni
  • Ẹgbẹ awọn oluka Bibeli, Bible Society of Nigeria, lo ba Kumuyi tẹ bibeli naa sita
  • Kumuyi sọ pe o jẹ ọkan lara awọn Bibeli òde oni, to ṣe e gbarale, to si rọrun julọ lati kà
  • Ẹgbẹrun mẹta ati ọtalelẹgbẹrin din mẹwaa Naira (₦3,750) ni wọn n ta ẹyọ kan Bibeli naa
  • Bibeli naa jẹ kikọ ni ilana èdè Yoruba ode oni, nípa ṣíṣe agbeyẹwo awọn ọrọ akọtọ ati gbolohun ede Yoruba to ti yi pada kuro ni ti àtijọ́
  • Ilana lori bi a ṣe n pe ọrọ Yoruba kọọkan, ati itumọ awọn ọrọ to ta koko
  • Kumuyi sọ pe Bibeli naa wulo fun ẹ̀kọ́ Bibeli ati iwaasu, bẹẹ ni ko yi ohunkohun pada ninu Bibeli to ti wa tẹlẹ.

Ni nkan bi ọdun 1850 ni wọn kọkọ gbe Bibeli jade ni èdè Yoruba, lati ọwọ Oloogbe Ajayi Crowther, to jẹ ọmọ bibi ìlú Osoogun nipinlẹ Oyo.

Ki ni Kumuyi se fun ọmọ Yoruba?

Bawo ni o ṣe yẹ ki awọn adari ẹsin maa sọrọ nipa awọn adari oṣelu?

Ibeere yii lo jẹ yọ ni ọjọ Aje bi ọpọ ọmọ Naijiria ṣe n bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Adari ijọ Deeper Life, Pasitọ William Kumuyi lori ọrọ rẹ nipa olori Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari.

Kumuyi sọ ni iwaasu rẹ ni ijọ olu ijọ Deeper Life to wa ni Gbagada nilu Eko pe ko tọ si ọmọ Naijiria lati maa bẹnu ẹ̀tẹ́ lu awọn adari wọn.

Alufaa Kumuyi ni, "Ẹ ma bẹnu ẹ̀tẹ́ lu adari Naijiria. Ẹ ma sọrọ alufansa si i lori ayelujara, Facebook, iwe iroyin tabi Twitter.

E ma ṣe oun kankan si i, nkan ti ko buyi kun un ni."

Alufaa naa ni ki ọmọ Naijiria bu ọla fun ẹni ti ọla ba tọ si.

O tun ni ki awọn ọmọ Naijiria ma bẹnu ẹ̀tẹ́ lu awọn gomina ati awọn olori ilu, ni ọpọ awọn to ka iroyin naa ba lọ ori Twitter lati tabuku arọwa alufaa naa.

Minisita fun eto irinna ofurufu nigba kan ri, Femi Fani-Kayode ni ọrọ Kumuyi yii jẹ ibanujẹ fun awọn akọni to ti ja fun ẹsin Kristẹni ni atijọ.

Reno Omokri to jẹ oluranlọwọ pataki Aarẹ ana, Goodluck Jonathan, ni ti aarẹ ba ṣe daradara, oun maa n gboriyin fun un, ṣugbọn to ba ṣe nkan abuku, oun yoo tun bẹnu ẹtẹ lu u.

O ni Bibeli ti Kumuyi ti yan ọrọ rẹ naa ni oun n tẹle lati ba wọn sọrọ atunṣe s'awọn adari ti kọ ba ṣe daradara.

Sẹnetọ Shehu Sani naa sọ si ọrọ naa. O rọ Kumuyi ki o jẹ ki ọmọ Naijiria fi ero wọn han lori awọn adari wọn.

Ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria kan ni ko si oun to buru ninu ọrọ Kumuyi naa.

Awọn kan ni ootọ ọrọ ti ko ni ki a ma sọ ohun ni ọrọ Babab Kumuyi

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ si: