Gbenga Adeboye: Àwọn olúlufẹ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lóri ǹkan ti wọn pàdánù lẹ́yìn ogún ọdún tó dolóògbé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọjọ Aiku ọgbọn ọjọ oṣu kẹrin ọdun 2023 yii lo pe ogun ọdun ti gbajumọ alawada ati sọrọsọrọ, Elijah Oluwagbemiga Adeboye ti ọpọ eeyan mọ si Fúnwọntán, Alhaji pastor Olúwo, Abẹfẹ, Jengbetiele, Itu baba ita, Alaye mi Gbengulo jade laye.

Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.

Ninu ifọrọwerọ kan ti iyawo rẹ, Lara ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin 'The Punch' lawọn asiko kan sẹyin, O ni igba gbogbo loun ṣi maa n saaro ọkọ oun nitori ipa rere to ko ninu aye oun atawọn ọmọ gẹgẹ bi ọkọ ati baba daradara.

Baba kan naa, Seun Adeboye to jẹ aburo oloogbe naa pẹlu ṣe apejuwe rẹ gẹgẹbi akanda ọmọ. O ni lootọ omi awada n ṣan ninu ẹbi awọn ni nitori pe bẹrẹ lati ori awọn obi awọn titi kan ọkọkan awọn ọmọ lo jẹ alawada, 'ṣugbọn ti Gbenga da yatọ nitori pe o sọ ọ di iṣẹ aṣela ati aṣejẹun. Alawada ni ṣugbọn o jẹ ẹni to duro ṣinṣin ninu gbogbo nkan to ni igba ninu rẹ."

Ọ̀gbẹ́ni Adeboye, tó jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, adẹ́ẹ̀rínpòṣúnú, àti akọrin ṣaaju ikú rẹ̀, jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lẹ́ka àwọ̀n amúlùdún, tọ́pọ̀lọpọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ sí fi ṣe àwòkọ́ṣe.

Elijah Oluwagbemiga Abefe Adeboye ni orukọ abisọ rẹ, amọ Alhaji, Pastor, Olúwo, Jengbetiele, Itu baba ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ míràn tó pani lẹ́rìn lo n jẹ lẹnu isẹ.

O tẹ baba mi lọrun pe ka mu gaari nile ju ki ebi pa ara ita lọ - Damilọla, ọmọ Gbenga Adeboye

Ninu ọr ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Damilọla ba BBC Yoruba sọ lawọn asiko kan, iwuri nla lo n jẹ fun oun atawọn aburo oun pe lati igba ewe oun titi ti oun tun fi dagba, awọn iṣẹ rere ti baba oun ṣe ati ipa to ni ninu igbe aye ọpọlọpọ ṣi n fọhun sibẹ.

"Mo kere nigba ti baba mi (Gbenga Adeboye) ku ṣugbọn gbogbo nnkan ti mo ti ri lati igba kekere mi titi ti mo fi dagba, baba mi jẹ ẹni ti gbogbo aye nifẹ si. Mi o mọ ibi ti wọn ti ri ẹbun ti wọn ni nitori o jẹ awodamiẹnu"

O ni alaanu ni Gbenga Adeboye nitori ko si ẹni ti kii ṣore fun. O si jẹ ẹni to ko gbogbo eeyan mọran gẹgẹbi ọ̀mọ ara rẹ tabi ẹbi rẹ gangan.

O fi kun un pe ọpọ igba ni Baba awn yoo ti ode iṣẹ de ti yoo ti fi gbogbo owo to ba pa nibẹ ṣaanu tan ti ebi yoo si maa pa awọn nile.

Woli Ọlọrun ni Gbenga Adeboye - Yinka Ayefẹlẹ

Ninu ọrọ tirẹ, gbajumọ olorin ati oludleeṣẹ silẹ, Yinka Ayefẹlẹ ṣe apejuwe Gbenga Adeboye gẹgẹbi woli Ọlọrun.

Ninu ọr to ba BBC News Yoruba sọ, Ọgbẹni Yinka Ayefẹlẹ MON ni Gbenga Adeboye wa lara awọn to kọkọ sọ asọtẹlẹ fun oun pe ogo ati irawọ oun ṣi maa tan kọja ibi ti oun funra oun lero.

O ni bi o ti wu oun pe ki o ba irọrun de, ọna inira ni ogo oun maa ba jade.

"Nigba ti ogo naa maa de ibi ijamba ọkọ lo ba bẹrẹ. Titi ti mo fi n sọrọ yii, ko si igba ti mi kii ni irora ni ibi igba aya ti mo fi gba itọkọ lọjọ naa. Ogo yẹn wa lootọ, kariaye wọn mọ mi lootọ ṣugbọn irora yẹn ti Gbenga Adeboye sọ lọjọ naa lọhun ṣi wa nibẹ."

Àwọn nǹkan málègbàgbé nípa Gbenga Adeboye

Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.

Láti túbọ̀ ṣe ìràntí Gbẹnga Adeboye, A ṣe àkójọ àwọn nǹkan mánigbàgbé mẹ́wàá tó ti ṣe nile aye.

1. Gbenga Adeboye lo sọ awada di itẹwọgba kaakiri

Gbenga Adeboye ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Funwọntan, ni ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tó sọ àwàda kẹrikẹri dí iẹwọgba gbogbo ènìyàn, kí àwọn ènìyàn mii tó lájú síbẹ̀.

Títí di àsìkò yìí, kò tíì ṣí ẹni tí o le ti ẹsẹ̀ bọ bata Gbenga Adeboye láti àsìkò yii titi di igba tó lọ sinmi láyà Oluwa.

Lẹ́yin àìsàn tó niṣe pẹ̀lú kídìrín ní Gbega Adeboye gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.

2. Gbenga Adeboye lo ni orukọ inagijẹ to tii pọju lẹnu isẹ:

Nígbà tí a bí Gbenga Adeboye, Elijah Oluwagbemiga Adeboye ni wọn sọ ọ́, sùgbọ́n nígbà tí yóò fi kú, o níra láti le sọ iye orúkọ tó n jẹ́ lẹnu isẹ.

Ìdí ni pé nínú orín àti àwàdà tí o má n ṣe, ló ti jẹ́ oníruurú orúkọ bii Funwontan, Alhaji Pastor Oluwo, Jengbetiele, Itu baba Ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ mííràn.

Gbenga Adeboye ni ẹbun pupọ ti ko se ka

Gbenga Adeboye jẹ ọkan ninu àwọn to ni ẹbun púpọ, ti o sì ni ìmọ̀ tó pọ̀ nínú iṣẹ̀ tọ yàn láàyò.

Kò sí ìgbà tó bá ń ṣe ohunkóhun ki àwọn ènìyàn má rín ẹ̀rin àrìn tàkìtì, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, oludari ayẹyẹ lóde àríyá ni pẹlu, bakan naa lo tu maa n kọrin.

3. Oloju aanu ati Onididun ọlọrẹ ni Gbenga Adeboye

Nígbà ayé rẹ̀ àti lásìkò tó kú tan, gbogbo ènìyàn ló n jẹ̀rí si pé Gbenga Adeboye jẹ́ onínu dídùn ọlọ́rẹ ati ẹni ti kò máyé le rara.

Ọ̀kàn nínú ọ̀mọ̀ Funwọntan lo fi idi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún BBC lásíkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

"O yá bábá mi kí a mú gàrí ju kí ará ìta má ri ounjẹ jẹ lọ."

4. Amunimọna ni Gbenga Adeboye, paapaa awọn to sẹsẹ n didelẹ:

Ọ̀pọ̀ ló má a n pè Gbenga Adeboye ni olùtọ́nisọ́nà fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde ni Alayé mi Gbengulo, bi ọ̀pọ̀ ṣe má a n pè é.

Ìròyìn fi ye ni pé, Gbenga Adeboye lo jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ gbájúgbàjà òṣèré Fathia Balogun bii isana ẹlẹẹta nítorí pé ó ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ijó orin rẹ̀ kan.

Àwọn ènìyàn bí Baba Gboin, Ereke ni Sọobu àti àwọn mííràn ló ti ara Adeboye dide pẹlu.

5. Ọjọru jẹ ọjọ ọ̀wọ̀ fun Gbenga Adeboye, kii fi sere rara:

Gbenga Adeboye jẹ́ ẹni ti kìí fi Ọjọ́rú ṣere nígbà ayé rẹ̀, abúrò rẹ̀ kan lo fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ nínú àwo orin kan tó gbé jáde.

Ninu awo orin naa lo ti sọ ìtàn ayé Gbenga Adeboye kí ó tó di ìlúmọ̀ọ̀ká lásìkò náà, Ọmọ Majẹmu lo pe àkọle orin náà.

Ọjọ́rú jẹ́ ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Gbenga Adeboye, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹsan ọdun 1959 ni wọ́n bíi

Ọjọ́rú ló bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, Ọjọ́rú bákan náà ló rin ìrìnàjò àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Amẹrika, Ọjọ́rú náà lo ṣe ètò Radio rẹ̀ àkọ́kọ́.

Ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù kẹrin ọdún 2003 lo kú, wọ́n sì sí ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrinlà, oṣù karun ọdún 2003.

6. Gbenga Adeboye ri ọrun, ko to ku

Wọ́n máá n ri Gbenga Adeboye gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti rí ọ̀run, kí ó tó kú.

idi ni pe o ti kọkọ ku nile iwosan, ti okiki si ti gba aye kan, ko to tun wa ji pada, ko si pẹ lẹyin igba naa, to tun jade laye pada.

Asiko perete to lo laye lẹyin iku rẹ akọkọ naa si lo gbe awo orin kan sita, ninu eyi to ti sọ bi ọrun se ri ati iriri ranpẹ to ni lajule ọrun nigba iku rẹ akọkọ.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú àwo orin naa, o ni òun kú, òun si rí Ọlọ́rún, sùgbọ́n ó dá òun pada láti lọ pari iṣẹ́ tó ran òun láti gbé ilé ayé ṣe ni.

Bákan náà lo ni Ọlọrun sọ fún oun pé, tí òun bá kú, wọ́n gbọdọ sin òun pẹ̀lú Bíbelì àti ìwé orin.

Àwo orin rẹ̀ yìí si lo dá onirúrú awuyewuye sílẹ̀ láwujọ lásìkò náà.

BBC Yoruba ba àwọn to ti ni ìbáṣepọ̀ kan tàbi omíràn pẹ̀lú olóògbé Gbenga Adeboye, nígbà ayé rẹ̀

Lárá àwọn iṣẹ́ ti Gbenga Adeboye ti ṣe ni ọmọ Majẹmu, ọ̀rọ̀sùnnùkùn 1&2 Ph.D Beetle, Fúnwọntán 1&2 ọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ mímọ 1&2, Versatility, Aiyetoro, Controversy, Supremacy, ijinlẹ àti Laisi Abesupinlẹ

Lójú òpó Twitter, ọ̀pọ́ ènìyàn ló n ṣeléde lẹ́yìn akọni

Gẹ́gẹ́ bi ìtàn ṣe sọ ọjọrú jẹ ọ̀kan pàtàkì láye olóògbé, a bíi ni ọjọrú, ọgbọ̀n ọjọ, oṣù kẹsàn ọdún 1959, ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ní ọjọrú, ìrìnajò akọkọ rẹ̀ lọ si ilẹ̀ Amẹrika jẹ ọjọrú, ètò orí rẹdiò àkọkọ wáyé lọjọrú bákan náà ló kú lọjọrú, ọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹ́rin ọdun 2003, ti wọn sín-ín ní ójórú, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kaàrún ọdún 2003.

Lara àwọn ǹkan ti Gbenga Adeboye gbá ayé ṣe

Gbénga Adeboye tí fi ọ̀wọ̀ kàn ayé ọ̀pọ̀ ti a sì n rí lónìí, lára wọn ni Yinka Ayefele, Fathia Balogun, Ereke ni Sọọbu, Bashiru Adisa ti gbogbo ènìyàn mọ si Baba Gbọin