You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Donald Trump ti gúnlẹ̀ sí UK fún àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́ta
Lojo Iṣẹgun ni ipade aarẹ Trump ati Theresa May yoo bẹrẹ.
Abẹwo aarẹ Trump ṣe kongẹ pẹlu iranti ikariudinlọgọrin D -Day Landings ti Obabinrin Elizabeth àti aarẹ Trump atawọn olori orilẹ-ede miran a jọ ṣe ni ọjọru.
Donald Trump ti pàdé Ọbabìnrin Elisabeth tilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì
Eto ikini-kaabọ n lọ lọwọ ni aafin Obabinrin ilẹ̀ Gẹẹsi fun aarẹ Amerika, Donald Trump.
Eto igbalejo ounjẹ ọsan yii kò wa fun gbogboogbo ni ilu Ọba.
'Air Force One' ni ọkọ baalu to gbe Trump wa si UK nibi ti wọn ti kọkọ lọ si ọdọ aṣoju ilẹ Amerika fun UK ni agbegbe Central London.
Ṣaaju ki ọkọ afurufu Trump to balẹ lo ti bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Sadiq Khan to jẹ olori London lẹyin ìkọlu wọn atẹyinwa.
Aàrẹ Donald Trump àti Melania aya rẹ̀ ti n jẹ oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lù Obabìnrin Elisa ni Buckingham Palace.
Ìfẹ̀hònúhàn ni àwọn ará UK fi ki Donald Trump káàbọ̀
Odindin ọjọ́ mẹ̀ta ni Trump a lo ni ilẹ̀ Gẹẹsi.
Aarẹ Donald Trump to n dari ilẹ Amerika ati iyawo rẹ, Melania Trump ni wọn jọ de si UK bayii.
Papa iṣere Stansted lo balẹ si ti wọn ti lọ kii kaabọ.
Abẹwo yii ti bi awọn ifẹhonuhan lawọn ẹkun bii London, Manchester, Belfast, Birmingham.
Awọn ikọ 'Stop Trump Coalition'ati 'Stand Up to Trump' ni awọn a jọ ṣe iwọde naa ni.
Ninu abẹwo ọlọjọ mẹta yii ni Trump yoo ti ṣe ipade pọ pẹlu Theresa May to jẹ olootu to ti kọwe fipo silẹ bayii lori ọrọ ayipada oju ọjọ.
Bakan naa ni wọn yoo jiroro lori ọrọ ile ìṣẹ Huawei ti China ti Amerika yọwọ ẹ lawo lataari eto aabo.
Saaju abẹwo yii ni Trump ti fihan pe oun wa lẹyin Boris Johnson pe ko gba ipo Theresa May.
Awọn ibi ti aarẹ Trump a ṣabẹwo si ni Westminister Abbey ati ọdọ Omọba Charles ati aya rẹ.
Bakan naa ni Trump a kan si Obabinrin Elizabeth ni Burckingham Palace ninu abẹwo yii.
London, Manchester, Belfast àtàwọn ẹkùn míì ni wọ́n ti n fẹ̀hónúhàn lónìí fí kí aàrẹ Trump káàbọ̀ sí UK