You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Brexit: Ibò mọ́kàndínlógun péré ni Theresa May fi bọ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin
Àwọn ọmọ ile aṣofin Ilẹ Geẹsi dibo a ko ni igbékélé ninu rẹ mọ ni Ọjọru lati yọ adari ijọba Theresa May nipo, ṣugbọn o jajaboọ pẹlu ibọ mọkandinlogun.
May ni ibo okoolelọọdurun ati marun (325) ti awọn to si yọ nipo si ni ibo ọọdurun ati mẹfa (306).
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Igbesẹ̀ yii lo tẹ̀le ijakulẹ to ri nigba ti awọn ọmọ ile dibo lati maa ṣe atilẹyin fun adehun to ṣe pẹlu ajọ EU lori Brexit.
Ninu ọrọ rẹ lẹyin ibo naa, May ni oun yoo maa ṣiṣẹ lati ri pe oun mu gbogbo ireti wọn lori ibo itagbagba, ninu eyi ti wọn ti fi han wipe awọn fẹ fi EU sile, wa si imuṣẹ.
Bẹẹ ni o tun ke pe awọn olori ẹgbẹ oṣẹlu, lati ba oun ṣe ipade pọ ki wọn baa le fi ero inu wọn han nipa ọna to tọ nipa Brexit.