You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tọkọ-tayà Osinbajo kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbi Folu Adeboye
Ìyá Adeboye jẹ́ àwòkọ̀ṣe rere fàwọn obínrin ìwòyí
Igbakeji ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo, tí dáwọ̀ọ́ ìdùnnú pẹ̀lú ìyàwó adari ìjọ ìràpada (Redeemed Christian Church of God), Olusọaguntan Folu Adeboye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Osinbajo ní ó jẹ́ ohun ìdunnu lati ni iru arabinrin Folu Adeboye lawujọ àwọn obínrin gẹgẹ bíi oniwàásù àti àwokose fawọn obinrin.
Ó rọ awọn obinrin lati ni suuru pẹ̀lú ẹbí wọn lai faaye gba iwa ipá ninu ile ati lawujọ pẹlu afiwe Iya Adeboye.
O ni àwọn ise ìrànwọ ti Iya Adeboye ń se fawọn ọ̀dọ́ àti àwọn alaini kò lẹ́gbẹ́.
Igbákeji ààrẹ, Ọjọgbọ́n Yemi Osinbajo gbadura kí Ọlọrun túbọ̀ lọ́ra ẹ̀mí wọn
Arabìnrin Folukẹ Adeboye pe ọmọ ààdọrun ọdún lori oke eèpẹ̀ lánàá.
Opọlọpọ eto ni awọn eniyan ṣe lati fi sami ayẹyẹ ọdun rẹ ti awọn èrò pupọ si n ki olukọ ati oniwaasu naa lori ayelujara kaakiri agbaye.