Highlighlight of Liverpool vs Chelsea: Liverpool pègúnrẹ́, wọ́n gbé ife ẹ̀yẹ̀ Premier league lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún

Balogun ikọ agbabọọlu Liverpool, Jordan Henderson gbe ife ẹyẹ Liigi ilẹ Gẹẹsi lalẹ Ọjọru ni papa iṣere Anfield.

Eyi ni igba akọkọ ti Liverpool yoo gba ife ẹyẹ naa laarin ọgbọn ọdun bayii.

Henderson tẹwọ gba ife ẹyẹ naa lọwọ ọkan lara awọn eekan agbabọọlu Liverpool, Kenny Daglish to jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa nigba ti wọn gba ifẹ ẹyẹ naa kẹyin lọdun 1990.

Ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹfa ni o ti fidimulẹ pe Liverpool ni olubori liigi Premiership ti ilẹ Gẹẹsi lọdun yii nigba ti o si ku ifẹsẹwọnsẹ meje ki saa liigi tọtẹ yii pari.

Lọjọ naa ni Manchester City to sun mọ wọn julọ lori atẹ igbelewọn liigi premiership ilẹ Gẹẹsi lọ fidirẹmi ni ile Chelsea lọjọ naa lọhun.

Nitori ajakalẹ arun coronavirus, ko si ẹyọ horo ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa kankan ni papa iṣire naa gẹgẹ bi o ti ṣe maa n ri.