You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus Update: WHO tí kéde pé Ó ṣeéṣe kí àrùn Coronavirus tànkálẹ̀ gba inú afẹ́fẹ
Ajo Eleto Ilera lagbaye, WHO ti kede pe o ṣeeṣe ki arun Coronavirus tan kale lati inu afẹfẹ.
WHO ni o ṣeeṣe ki afẹfẹ gbe arun naa ni ibi ti ero ba pọ si ati ibi ti ko ba si atẹgun, amọ ajọ naa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati fidiẹ mulẹ daadaa.
Wọn ni ti wọn ba fi idi ẹ mulẹ pe lootọ ni arun naa n tankalẹ lati inu afẹfẹ, yoo mu atunṣe si ofin iyansọtọ dani ni inu ile ni ibi ti eniyan ba pọ si.
- Mo kó àrùn Coronavirus lẹ́yìn tí mo ṣalábapàdé ẹni tó ní àrùn náà lára - Idris Elba
- Èèyan 35 ló ti ru àrùn Coronavirus la ní Naijiria
- Wo àwọn irọ́ ti ọ̀pọ̀ ń pa nípa Coronavirus!
- Màmá Guardiola d'olóògbé lẹ́yìn tó lùgbàdì Coronavirus
- Páro-páro ni àwọn mọ́ṣálááṣí dá káàkiri Nàìjíríà lásìkò ìrun Jímọ̀ nítorí coronavirus
Ohun ti Ajọ Eleto Ilera lagbaye, WHO n sọ tẹlẹ ni pe omi ara eniyan lo n fa itankalẹ arun naa. iyẹn, Ki o to di asiko yii o.
Awọn onimọ Sayẹnsi to le ni igba ni ajọ WHO sọ pe wọn kọ lẹta si Ajọ WHO lati ṣe ayẹwo boya arun Coronavirus n tankalẹ lati inu afẹfẹ.
Amọ, Ajọ Eleto Ilera, WHO ti ke si awọn onimọ Sayẹnsi naa lati fi aaye silẹ fun iwadii kikun lori boya arun Coronavirus le tankalẹ ninu afẹfẹ.
Wọn fikun un pe ti o ba jasi otitọ, ofin ṣiṣe gaaya si ara ẹni yoo yatọ si bi o ṣe wa bayii.
Awọn eniyan yoo nilo lati ma a yago fun ara ju tẹlẹ lọ paapaa ni awọn ile igbafẹ, ile ounjẹ ati ọkọ igboro lati dena itankalẹ arun naa.