Coronavirus Pandemic: Màmá Guardiola d'olóògbé lẹ́yìn tó lùgbàdì Coronavirus

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Afẹfẹ aarun coronavirus to n fẹ kaakiri ti fẹ de idile akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City,Pep Guardiola.

Iya Guardiola, Dolors Sala Carrió ti di oloogbe lẹni ọdun mejilelọgọrin lẹyin to lugbadi aarun covid-19.

Sala Carrió ku si Manresa, niluu Barcelona lorilẹede Spain.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City lo fọrọ naa lede loju opo Twitter wọn nibi ti wọn ti kẹdun pẹlu Guardiola lori iku mama rẹ.

Loṣu to lọ ni Guardiola gbe owo to le ni miliọnu kan owo dọla kalẹ lorilẹede Spain lati gbogun ti itankalẹ aarun coronavirus.

Bakan naa lo ṣe fido ninu eyi to ti gbawọn eeyan lamọran lati joko sile, ki wọn si tẹle awọn ilana tawọn oṣiṣẹ eto ilera la kalẹ lasiko yii.