Coronavirus : Idris Elba ti lùgbàdì àrùn Coronavirus

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja oṣere ọmọ ilẹ Gẹẹsi Idris Elba ti kede pe oun ti lugbadi arun Coronavirus.

Elba lo fi ọrọ naa lede ninu fidio kan loju opo Twitter rẹ.

O ni "Ni owurọ yii ni mo gab esi ayẹwo fun arun Coronavisur, esi ọhun si fi han pe mo ti ni arun naa."

Oṣere naa ni ṣaka lara oun da bayii ti ko si si apẹrẹ arun lara oun, ṣugbọn o ni oun ti wa ni ipamọ lati igba ti oun ti woye pe o ṣeṣe ki oun ti ko arun naa.

Elba sọ siweaju si pe oun ṣalabapade ẹni kan to ti ko arun naa lo jẹ ki oun lọ fun ayẹwo.