You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Orílẹ̀-èdè Tanzania àti Somalia náà ti gbàlejò àrùn Coronavirus
Minisita eto ilera orilẹede Tanzania, Ummy Mwalimu ti kede pe arun Coronavirus ti tan de orilẹede naa.
Mwalimu sọ pe ọmọ ilẹ Tanzania kan to de lati orilẹede Belgium lọjọ karundinlogun Oṣu Kẹta ọdun yii lo ko arun naa wọle.
O ni obinrin naa ko ṣafihan apẹẹrẹ aisan naa nigba ti wọn ṣe ayẹwo ara rẹ ni kete to gunlẹ si papakọ ofurufu Kilimanjaro. Amọ, nigba to de yara igbalejo rẹ lo bẹrẹ aisan ranpẹ, ti ayewo si fi han pe arun Coronavirus ti n ba finra.
- Ìsìn ń lọ nínú ìjọ Sotitobire àmọ́ a kò le lu ìlù, gbogbo rẹ̀ ti jóná - Ọmọ ìjọ
- Wọ́n gbé òkú ọgá iléẹ̀kọ́ àti òṣìṣẹ́ méjì míì tó kú nínú ìbúgbàmù lọ sílé ìgbókùsí ológun ojú omi l‘Eko
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Coronavirus dá wàhálà sílẹ̀ ní Ghana, ìjọba gbé ìlẹ̀kùn gbogbo iléẹ̀kọ́ tìpa
Mwalimu ti rọ awọn ọmọ orilẹede naa lati ma foya nitori ijọba yoo ṣe gbogbo to yẹ ni ṣiṣe lati dẹkun itankalẹ arun naa lorilẹede naa.
Lẹyin naa lo wa fikun pe ijọba ilẹ naa ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari gbogbo awọn eeyan ti obinrin ọhun ṣalabapade ninu irin ajo rẹ lati Belgium si Tanzania lati le ṣayẹwo wọn.
Baakana, ijọba orilẹ-ede Somalia ti kede pe wọn ti gbalejo arun Coronavirus lorilẹ-ede wọn.
Minisita eto ilera Somalia, Fowsiya Abukar sọ fun awọn akọroyin pe ọmọ ilẹ ọhun kan to ṣeṣe de lati oke okun lo ko arun Coronavirusa wọle.
O ni ijọba ti gbẹsẹ le gbogbo ohun to jọ mọ irin ajo oke okun nilẹ naa fun ọsẹ meji gbako, bẹrẹ lati ọjọ kejidinlogun Oṣu Kẹta ọdun yii lati le dekun itankalẹ ajakalẹ arun naa.
Ghana ní kò gbọdọ̀ sí ìsìn mọ́ láwọn ṣọ́ọ́ṣì àti mọ́ṣálásí fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin
Ijọba Ghana gbe ilẹkun gbogbo ileẹkọ tipa lati dekun itankalẹ Coronavirus
Kaka ki ewe agbọn arun asekupani Coronavirus dẹ, ko ko ko lo n le si jakejado agbaye, to si ti n kan si ilẹ Afirika pẹlu.
Lọwọlọwọ bayii orilẹede Ghana, to mule ti ilẹ wa Naijiria ti sọ agadagodo sawọn ẹnu ọna ileẹkọ rẹ, to fi mọ awọn ileẹkọ giga fasiti, titi di ọjọ mii, ọjọ re.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Àwọn kókó ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Aláàfin kọ sí Fayemi rèé
- Ọmọ ti lọ kí baba, Fayemi bẹ Aláàfin wo l‘Ọyọ, wọ́n jírórò lórí lẹ́tà
- Ìlú ò rẹ́rìn ín rárá, Alaafin Adeyemi III fárígá fún Buhari nínú lẹ́tà tuntun
- Àwọn alálẹ̀ kò ní forí jìn mí tí ń kò bá ṣe ọdún Ṣàngó - Alaafin
Bakan naa lo tun kede pe ko gbọọdọ si eto kankan mọ nigboro to nii se pẹlu ipejọpọ ero lọna ati dena itankalẹ ọwọja arun asekupani Coronavirus.
Aarẹ orilẹede Ghana, Nana Akufo-Addo lo kede bẹẹ lasiko to n bawọn ọmọ orilẹede naa sọrọ pẹlu afikun pe, ko gbọdọ si ipade apero kankan mọ, to fi mọ isin laarin awọn ẹlẹsin, idije ere idaraye ati iwọde awọn oloselu, fun ọsẹ mẹrin gbako.
Bakan naa nijọba ilẹ Ghana tun ti kede pe, ọmọbibi ilẹ naa to ba ti lọ si awọn orilẹede tawọn alarun Coronavirus ibẹ ju igba lọ, laarin ọjọ mẹrinla sẹyin ko ni ni anfaani lati wọle pada si orilẹede naa.
Ijọba orilẹede Ghana ti kede fawọn ileesẹ ọkọ ofurufu pe ki wọn mase gbe ero wa si orilẹede Ghana, lati awọn orilẹede ti arun Coronavirus n ba finra.
Ijọba ni oun gbe awọn igbesẹ ọhun lati dẹkun bi ọwọja arun Coronavirus to n ja kiri eyi to ti mu ki awọn eeyan to ni arun naa lorilẹede Ghana di mẹfa, lati meji to wa tẹlẹ.
Ọmọ oṣù mẹ́rin ní Coronavirus ní Cambodia, Turkey ya 10,000 sọ́tọ̀
A maa n pe ọrọ arun asekupani yii ni òwè, amọ ni bayii, o ti n ni àáró nínu nitori awọn orilẹede lagbaye lo ti n gbe awọn igbesẹ to lagbara lati kawọ arun naa ko.
Turkey ya 10,000 eeyan sọtọ:
Idi ni pe ko din ni ẹgbẹrun mẹwa arinrinajo ẹsin to de lati orilẹ-ede Saudi Arabia l'opin ọsẹ ti wọn ti ya sọtọ bayii ni Turkey, eniyan mẹjọ lo si ti ni arun Coronavirus lorilẹede naa bayii.
- Àǹkóò àrùn coronavirus dé orílẹ̀èdè Togo
- Coronavirus ti di àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé- WHO
- Àlárùn Coronavirus di 7000 lágbàyéé, ìjọba Nàíjíríà kọjú oro sí ọjà China tó jẹ́ ẹbu
- Èyí ni ohun tí a mọ̀ nípa afurasí aláàrùn coronavirus nípìnlẹ̀ Enugu
- Nàìjíríà bèèrè ìrànwó lọ́wọ́ àjọ àgbáyé láti kápá Coronavirus
Minisita fun eto ilera l'orilẹ-ede Turkey, sọ pe yara ọtọọtọ ni wọn fi ẹnikọọkan wọn si fun iyasọtọ, ni ankara ati ni ẹkun Konya to wa ni tosi.
Ọkan lara awọn arinrinajo naa, to ṣẹṣẹ de lati Saudi Arabia l'ọsẹ to kọja ni aarun naa lara.
Oṣu to kọja ni ijọba Saudi Arabia fi ofin de awọn arinrinajo ẹsìn lati ilẹ okeere pe, ki wọn o ma wa a si ilu Mecca ati Medina.
Ọmọ osu mẹrin ni Coronavirus nilẹ Cambodia:
Bakan naa ni orilẹ-ede Cambodia tun ti fidi eniyan mẹẹrin miran to ni arun naa lara mulẹ. Koda, ọmọ oṣu mẹrin naa wa lara wọn.
Baba ọmọ tuntun naa jẹ ọmọ orilẹ-ede France kan, to rinrinajo lati ilu Paris gba Singapore kọja lọ si Phnom Pehn. Ayẹwo fihan l'ọjọ Aiku pe, ọkunrin naa ni i, ṣugbọn iyawo rẹ ko ni i.
Bakan naa, ọkunrin ọmọ Cambodia kan to de lati France, ati awọn eniyan meji miran to de, lẹyin ti wọn lọ fun ayẹyẹ ẹsin Islam kan ni orilẹ-ede Malaysia naa ni arun asekupani yii
Eyi mu ki apapọ awọn to ti ni arun naa l'orilẹ-ede Cambodia jẹ mejila bayii.
South Africa fofin de arinrin ajo lati Amẹrika, UK ati Italy:
Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa sọ pe wọn yoo fi ofin de awọn ajoji lati orilẹ-ede US, UK, Italy ati awọn orilẹ-ede miran ti aarun naa pọ si, lọjọru.
O sọ pe lootọ ni yoo pa ọrọ aje lara, ṣugbọn awọn ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ coronavirus.
Bakan naa ni South Africa ti fofin de ipejọpọ eniyan to ba le ni ọgọrun, wọn si tun fẹ ti ilẹkun awọn ileewe.
Ajoji to ba niwe igbelu nikan ni yoo wọ Kenya:
Awọn ọmọ orilẹ-ede Kenya nikan, ati awọn ajoji to ba ni iwe igbelu ti ọjọ ko ti i lọ lori rẹ nikan, ni wọn yoo faaye gba lati wọle si Kenya.
Eniyan mẹta ni wọn ti kede pe o ni aarun naa ni Kenya.
Lọwọlọwọ, orilẹ-ede mẹrindinlọgbọn lo ti ni aarun naa l'agbaye.
Eniyan to le ni ọọdunrun lo si ti ni i nilẹ Afica. Egypt, Senegal, ati South Africa si lo pọ si julọ.
Los Ageles gbe ilẹkun ile ounjẹ, ile ijo ti pa
Olootu ijọba Los Angeles l'orilẹ-ede America, Eric Garcetti ti paṣẹ pe, ki gbogbo awọn ile ọti, ile ounjẹ, ati ile ijo to wa nilu naa gbe ilẹkun wọn ti.
Aṣẹ yii jade lẹyin wakati diẹ ti ijọba ilu New York naa ṣe bẹ ẹ.
Ẹgbẹrun marun lo ti ni Coronavirus ni Germany:
Ninu iroyin miran, eto agbelewo kan to n lọ lori amohunmawoaran ni Germany lati ọjọ kẹfa, oṣu Keji, nibi ti awọn to olukopa ti wa ni ilu ile kan naa, ti wọn ko ti ẹ ti i gbọ nipa aarun COVID-19.
Ko ti foju han boya ẹnikẹni ti ẹ fi to wọn leti nipa aarun naa. Awọn kan n se faaji lọ ni ti wọn ni.
Eniyan bi ẹgbẹrun marun lo ti ni Coronavirus ni Germany.