Coronavirus: Nàìjíríà sọ àgádágodo sí ilé ìtajà China l‘Abuja láti dènà ìtànkálẹ̀ Coronavirus

Ajọ to n mojuto idaabo bo awọn araalu nipa ọja rira ni Naijiria, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), ti sọ agadagodo si ile itaja awọn ọmọ orileede China kan nilu Abuja, Panda Supermarket.

Igbesẹ yii, gẹgẹ bi ajọ naa ti ṣe sọ jẹ ọna lati koju itankalẹ aisan Coronavirus.

Loju opo Twitter wọn ni ajọ naa fi ikede yii sita, ti wọn si ṣe afihan awọn ounjẹ ti ile itaja naa n ta, eyiti wọn gbe wọ Naijiria lọna ti ko tọ.

Tunde Irukera, to jẹ ọga agba ajọ naa lo ko awọn ọlọpaa sodi, lati lọ ti ile itaja naa pa lẹyin to ni awọn kan ta oun lolobo pe ayederu ọja wa lara nkan ti wọn n ta nibẹ.

Ninu awọn aworan ọja ti wọn fi si oju opo wọn, a ri wi pe ọjọ ti rekọja lori awọn ohun jijẹ kan ti wọn n ta nibẹ.

Irukera sọ pe awọn yoo gbe awọn ounjẹ wọn yii kuro lori igba lati le fi daabo bo ara ilu.

Ẹwẹ, iye eeyan to ti ba iṣẹlẹ ajakalẹ aisan coronavirus ti di 170 bayi, ti wọn si ti kede pe o ti tan kalẹ de gbogbo agbegbe China.

Awọn alaṣẹ ilẹ China ni awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun meje ni aisan naa ti n ba finra bayi. Itankalẹ rẹ si ti de awọn orileede mẹrindinlogun lagbaye.

Lọjọbọ ni ajọ ilera agbaye yoo ṣe ipade pajawiri, lati jiroro lori ipenija aisan coronavirus.