You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sotitotbire: Ilé ẹjọ́ dá Alfa Babatunde padà sí áhàmọ́ọ́ bẹ́ẹ̀ni ó tún sún ìgbẹ́jọ́ si Ọjọ́-Bo̩
Ile ẹjo ti sun igbẹjo si ọjọ Ọjọbo. Agbẹjọro fun ijọba inpinlẹ Ondo, to jẹ olupẹjo, so wi pe, botilẹ̀ jẹ pe ko wu ijọba lati jẹ ki ẹjọ naa pẹ nilẹ, agbẹjọro fun Sotitobire bẹbẹ ki ileẹjọ sun igbẹjọ naa siwaju.
Ọmọ ijọ Sotitobire kan, to wa nile ẹjọ lọjọ Aje, lasiko ti igbẹjọ asaaju ijọ naa n lọ lọwọ lori ẹsun ijọmọgbe ti ba BBC Yoruba sọrọ.
Ninu ifọrọwerọ naa, eyi to da lori ipo ti ijọ ọhun wa lasiko yii ti olori ijọ, Alfa Babatunde wa lọgba ẹwọn, ọmọ ijọ naa, to pe orukọ ara rẹ ni Yetunde salaye pe nkan ko dabi bo se n waye tẹlẹ rara.
- Àwọn abiyamọ figbe ta lórí ọmọ ọdún kan ti wọn wá nílé ìjọsìn l'Akure
- Mo kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire ni - Afurasí
- Ẹ má gbàbọ̀de kankan láti tú Wolii ìjọ Sotitobire sílẹ̀ o! - Ọọ̀ni Ife
- Ìgbẹ́jọ́ aṣaájú ìjọ Sotitobire kúrò nílé ẹjọ́ Mágísíréètì lọ sílé ẹjọ́ gíga l‘Akure
- Bayìí ni àwọn ọlọpàá Akure ṣe ko àwọn ará ìlú ti o ji ẹrù ni sọọsi Sotitobirẹ
Yetunde ni lootọ ni isin n waye nile ijọsin Sotitobire amọ awọn ko lee lu ilu rara nitori gbogbo rẹ ni awọn oluwọde kan ti sun nina, lasiko ti wọn se iwọde wa sile ijọsin naa.
"Isìn ń tesiwaju pelu pé kò sí Àlùfáà Babatunde ni itosi, amọ lóòótọ́, kò dabi ìgbà tí bàbá wá nílé, kò sì ìlú lílu nítorí pe gbogbo àwọn èròjà wonyii ni wọn ti jo nina."
Igbẹjọ Alfa Babtunde si n lọ lọwọ, a mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.
Iléẹjọ́ kún fọ́fọ́ fún èrò nítẹ̀síwájú ẹ̀ṣùn ìjọ́mọgbé tí wọn fi kan aṣaájú ìjọ Sotitobire
Ileẹjọ giga ilu Akurẹ tun kun fọfọ lọjọ Aje nitẹsiwaju ẹjọ Asaaju ijọ Sotitobirẹ, Alfa Babatunde, tijọba ipinlẹ Ondo fi ẹsun ajọmọgbe kan.
Bẹẹ ba gbagbe, lati osu kẹjọ ọdun 2019 ni isẹlẹ kan ti waye ninu ijọ Sotitobire nilu Akure pe, ọmọ ọdun kan, Gold Kọlawọle sọnu ninu ijọ naa, ti wọn ko si ri di akoko yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Coronavirus dá wàhálà sílẹ̀ ní Ghana, ìjọba gbé ìlẹ̀kùn gbogbo iléẹ̀kọ́ tìpa
- Iṣẹ́ akin ni ọ̀gá iléẹ̀kọ́ tó kú nínú ìbúgbàmù Eko ṣe, ẹ fàmì ẹ̀yẹ da lọ́lá - PDP késí ìjọba
- Rẹ́rẹ́ rún níbi ìbúgbàmù l'Eko, ọ̀pọ̀ àwòrán rèé
- Gbogbo ẹ̀yin tẹ fẹ́ yọ Oshiomole nípò, ẹ kò moore, ìwà yín ń kóbá APC - Tinubu
Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Ondo fi gbe asaaju ijọ naa ls sile ẹjọ lẹyin ti gbogbo aayan lati ri ọmọdekunrin naa ja si pabo.
Nibi igbẹjọ losu to kọja, ni adajọ ile ẹjọ giga, to gba ẹjọ naa lọwọ ileẹjọ majisireti ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Aje, ọjọ Kẹrindinlogun, ikẹtadinlogun ati ikejidinlogun osu kẹta ọdun yii.
Ni deede aago mẹsan aarọ si ni awọn osisẹ ọgba ẹwọn ti gbe Alfa Babatunde de sileẹjọ ati awọn afurasi ọmọ ijọ rẹ miran ti wọn fi ẹsun ajọmọgbe kan pẹlu rẹ.
Asọ alawọ eweko, tii se asọ ọgba ẹwọn si ni Babatunde wọ wa sile ẹjọ, ti wsn si fi ọkọ ọgba ẹwọn bọọsi kan gbe wa sibẹ.
Bi igbẹjọ naa ba se lọ, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.