Yemi Osinbajo: Ẹgbẹ́ Arewa ní ọ̀rọ̀ ìgbákejì ààrẹ tún dákún ìṣòro Nàíjíríà ni

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lorilẹede Naijiria ti satilẹyin fun igbakeji aarẹ lorilẹede, Yemi Osinbajo lori ọrọ to sọ pe, o ṣeeṣe ki Naijiria pin ti awọn adari ko ba kiyesi ara.

Osinbajo, ti akọwe ijọba, Boss Mustapha soju fun, sọ eyi lasiko isin ayẹyẹ ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira, eyi to waye nilu Abuja.

Osinbajo ni ogiri to gbe Naijiria ro n mi titi, eleyii to le fa ki Naijiria wo lulẹ, ti wọn ko ba kiyesi ara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ tirẹ, Akọwe ẹgbẹ afẹnifẹre, Yinka Odumakin ni, ọrọ akọni ni Osinbajo sọ, eleyii to fihan wi pe, ko ṣe magomago pẹlu gbogbo iṣẹlẹ to n waye ni Naijiria.

Odumakin fikun wipe, o pọn dandan ki ijọba wa ọna abayọ si iṣoro to n koju awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni Ẹgbẹ awon ẹya Igbo, Ohanaeze Ndigbo ni o dara bi Osinbajo ṣe sọrọ lori iṣoro to n koju awọn ọmọ Naijiria, ati bi o ṣe le jasi ipinya fun wa.

Ohanaeze ni amọ awọn tako Osinbajo lori ọrọ rẹ wi pe adura ni ọna abayọ.

Ohanaeze ni adura nikan kọ ni ọrọ Naijiria gba bayii, nitori ijọba gbọdọ wa ọna abayọ si iṣoro ipaniyan awọn Fulani darandaran laarin awọn iṣoro ti Naijiria n koju.

Ninu ọrọ ti wọn, Ẹgbẹ Pan Niger Delta Forum, PANDEF ni atunto ni ọna abayọ si iṣoro Naijiria, eleyii ti yoo fun awọn ijọba ipinlẹ ni agbara lati mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba agbegbe wọn.

Ajọ PANDEF fikun wi pe awọn ẹgbẹ ni Naijiria bi IPOB ati awọn miran to n bere fun ominira ẹya wọn fihan pe ina wa lori orule orilẹede Naijiria.

Amọ, ẹgbẹ awọn ẹya ariwa orilẹede Naijiria, northern socio-political group, the Arewa Consultative Forum, ACF ni ọrọ kubakugba ni Osinbajo sọ, bi o tile jẹ wi pe lootọ ni iṣoro lorisirisi n koju Naijiria.

ACF fikun pe, ọrọ Osinbajo tun dakun wahala to wa nlẹ ni nitori awọn ọrọ to sọ lẹnu le fa ẹtanu ati ija.

ACF ni awọn gbagbọ pe laipẹ Naijiria yoo bori gbogbo iṣoro to n la kọja, ni ọna ati mu irọrun ba awọn ọmọ Naijiria.

Ọmọ Nàìjíríà sọ òkò ọ̀rọ̀ sí Osinbajo lórí ìkíni rẹ sí Wole Soyinka

Yoruba ni pẹlẹ ni akọ, to si tun labo, Ọlọrun ma si jẹ ka si ọrọ sọ.

Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ pẹlu ọrọ ti Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo kọ soju opo Twitter rẹ lati ki Ọjọgbọn Wole Soyinka ku ọjọ ibi ọdun kẹrindinlaadọrun loke eepẹ.

Osinbajo ni "Ẹ ku ọjọ ibi, Ọjọgbọn!...ẹ pẹ laye lati ri orilẹede Naijiria bẹ ṣe fẹ ko ri"

Ṣugbọn ṣe ni awọn ọmọ ta gba igbakeji aarẹ lori ikini naa, ti wọn si n sọ oko ọrọ si pe ọrọ to sọ gbẹyin naa lo tabuku ikini rẹ si Soyinka naa.

Awọn kan wa n beere lọwọ aarẹ pe ṣe orilẹede Naijiria ni ala kankan to n fi oju sun ni, ti awọn miran si ni pẹlu ọpọ ẹsun ajẹbanu to wa lọrun awọn asaaju oloselu, ti Naijiria yoo de ibi to yẹ ko de bi?

Ọpọ ọmọ Naijiria ninu ọrọ yii lo si fi oju han pe wọn ti sọ ireti nu nipa orílẹede Naijiria.