You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀dọ́mọkùnrin ẹni ọdun mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ṣá bàbá rẹ̀, ẹni ọdún àádọ́rin pa
Arakunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan ni wọn fi ẹsun kan pe o pa baba rẹ, alagba Christopher Ogum ni ilu Umuomaku nijọba ibilẹ Orumba South nipinlẹ Anambra
Ṣọfẹli ikọle ni wọn ni o fi pa baba rẹ ti wọn ni ọjọ́ ori rẹ jẹ aadọrin ọdun ti o si sare sin in ni oloku oru sinu saare kan ti ko gbẹ jin pupọ.
Iroyin latẹnu awọn akọroyin iwe iroyin abẹle kan ṣalaye pe igbiyanju Chris afurasi naa lati sa mọ ofin lọwọ lo bọ si pabo pẹlu bi awọn ara adugbo ṣe mu u ti wọn si lu u bi ẹni maa ku .
Awọn aladugbo naa ni wọn fi ipa mu u lati fi saare to sin baba rẹ naa si han ti wọn si tun ni ko hu oku rẹ jade pada.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed ṣalaye pe ọwọ ti ba afurasi naa,
Ati pe wọn si ti gba irinṣẹ to fi ṣiṣẹ buruku naa lọwọ rẹ gẹgẹ bi ẹri lati lo nile ẹjọ́