World Cancer Day: Ènìyàn 26,000 ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa lóòjọ́

Ajọ Eto Ilera Lagbaye, WHO ti pe akiyesi awọn eniyan si ipa ti aisan jẹjẹrẹ n ko lawujọ, pẹlu akiyesi pe miliọnu mẹjọ eniyan ni yoo ku lọdun yii nipa aisan jẹjẹrẹ.

Ajọ Agbaye to ni akọri ti ọdun yii ni 'I am and I will', fikun wi pe ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn eniyan lo n ku lojoojumọ nitori aisan jẹjẹrẹ.

Ajọ naa fikun wi pe o ṣeeṣẹ ki o peleke si ninu ọdun yii pẹlu bi oju ọjọ ṣe n bajẹ si, ti igbe aye awọn eniyan o gbe pẹẹli si ati iru ounjẹ ti awọn eniyan n jẹ.

Kini awọn nkan to n fa aisan jẹjẹrẹ?

  • Ọjọ ori
  • Gbigbe igbe aye inira
  • Fifi taba lile ati oti mimu
  • Aisan inu ara
  • Sisanra lasanju le fa aisan jẹjẹre ọmu, ikun ati isalẹ inu pẹlu aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ.

Kini ọna abayọ si aisan jẹjẹrẹ

  • Ẹ ṣọra fun fifi taba
  • Ẹ jẹun ti ohun ṣe ara loore
  • Ẹ jẹ ọpọlọpọ eso ati ẹfọ.
  • Ẹ sọra fun sisanra lasan ju
  • Ẹ ma mu oti la muju.
  • Ẹ sọra fun jije ẹran ti wọn ti ṣe sibẹ tabi ti wọn ti fi sinu ike.
  • Ẹ ma a se ere idaraya pẹlu igbe aye to ni itumọ.
  • Ẹ ṣora fun oorun osan gangan, pelu aṣo to bo ara.
  • Ẹ ma lo si ile iwosan fun abere aje sara lati dena aisan bii Hepatitis B ati bee bee lo.
  • Ẹ ṣora fun ibalopo ai lo roba idaboobo.