You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emiliano Sala: Wón ti rí bààlú agbábọ́ọ́lù tó pòórá nínú òkun
Eyi to ku ninu ọkọ̀ ofurufu to gbe agbabọọlu Cardiff City, Emiliano Sala to poora ni wọn ti ri ninu okun to wa laarin Ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Faranse.
Baalu naa to jẹ Piper Malibu N264DB ni o sọnu ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu kini nigba to n lọ lati ilu Nantes ni Faranselọ Cardiff.
Agbabọọlu ọmọ Argentina naa ati arakunrin to tu'kọ naa, David Ibbotson nikan lo wa ninu rẹ.
Àwọn oluwadii ti ni awọn yoo ran ọkọ to n ṣe iwadii abẹ omi lọ sibi ti wọn ti ri ajaku baalu naa ni ọjọ Aje.
David Mearns, to n dari awọn to n wa ọkọ naa lati ọjọ to sọnu ni agbegbe Guernsey ni wọn ti ri ajaku ọkọ naa labẹ omi ni ọjọ Aiku.
Ileeṣẹ to n ṣe iwadii ijamba ọkọ ofururu ti wa ni ibẹ bayii lati gbe ajaku baalu naa jade.
Ọpọlọpọ ọrọ ibanikẹdun lo wọle lo ti n wọle lati igba ti ọkọ naa poora.
Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ Cardiff gba ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ lati igba ti baalu Sala ti poora ni ọjọ Abamẹta.