Lagos City Marathon: Sintayehu Legese láti Ethiopia ló jáwé olúborí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọmọ ilẹ Ethiopia, Sintayehu Legese lo jawe olubori ninu idije ipinlẹ Eko, Lagos City Marathon pẹlu ẹbun owo $50,000.

Wakati meji, o le isẹju mẹtadinlogun ni ẹni to gbe igba oroke naa lo lati fi sare lati papa isere ti Surulere de Eko Atlantic City.

Bakan naa, Ọmọ Naijiria to kọkọ kọja ori ila, Gideon Goyet yoo gba miliọnu mẹta naira lọ si ile, nigba ti ẹni keji ati ẹni kẹta to jẹ ọmọ Naijiria to kọkọ de ori ila naa yoo gba miliọnu meji ati miliọnu kan lọ sile.

Ẹni to jawe olubori lọdun to kọja, Joshuna Kipkorir lo se ipo keji ni ipele awọn ọkunrin lati ilẹ Ethiopia.

Obinrin akọkọ to kọkọ kọja ori ila ni Meleka Meseret Dinke lati ilẹ Ethiopia bakan naa.